Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 38:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Sefatíà ọmọ Mátanì, Gédáyà ọmọ Páṣúrì, Jéhúdù ọmọ Selemáyà àti Páṣúrì ọmọ Málíkíà gbọ́ ohun tí Jeremáyà ń sọ fún àwọn ènìyàn nígbà tí ó sọ wí pé,

2. “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Ẹnikẹ́ni tó bá dúró nínú ìlú yìí yóò kú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn; ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tó bá lọ sí Bábílónì yóò yè; yóò sá àsálà, yóò sì yè.’

3. Àti pé èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Ìdánilójú wà wí pé a ó fi ìlú náà lé ọwọ́ àwọn ọmọ ogun Bábílónì; tí yóò sì kó wa nígbékùn.’ ”

4. Nígbà náà ni àwọn ìjòyè wí fún Ọba pé, “Ó yẹ kí a pa ọkùnrin yìí; ó ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ ogun tó kù nínú ìlú pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn nípa ohun tí ó ń sọ fún wọn. Ọkùnrin yìí kò fẹ́ ire fún àwọn ènìyàn bí kò ṣe ìparun.”

5. Sedekáyà Ọba sì wí pé, “Ó wà lọ́wọ́ yín. Ọba kò lè ṣe ohunkóhunm láti ta kò yín.”

6. Wọ́n gbé Jeremáyà sọ sínú àmù Málíkíà ọmọ Ọbakùnrin tó wà ní àgbàlá àwọn ẹ̀ṣọ́, wọ́n ju Jeremáyà sínú àmù pẹ̀lú okùn; kò sì sí omi níbẹ̀ àyàfi ẹrọ̀fọ̀ nìkan, Jeremáyà sì rì sínú ẹrọ̀fọ̀.

7. Ṣùgbọ́n, Ebedimélékì, ará Kúṣì ìjòyè nínú ààfin Ọba gbọ́ pé wọ́n ti ju Jeremáyà sínú àmù. Nígbà tí Ọba jókòó lẹ́nubodè Bẹ́ńjámínì.

8. Ebedimélékì jáde kúrò láàfin ó sì sọ fún un pé,

Ka pipe ipin Jeremáyà 38