Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 37:5-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Àwọn ọmọ ogun Fáráò ti jáde kúrò nílẹ̀ Éjíbítì àti nígbà tí àwọn ará Bábílónì tó ń ṣàtìpó ní Jérúsálẹ́mù gbọ́ ìròyìn nípa wọn, wọ́n kúrò ní Jérúsálẹ́mù.

6. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Jeremáyà òjíṣẹ́ Ọlọ́run wá:

7. “Èyí ni, ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn Ísírẹ́lì sọ fún Ọba àwọn Júdà tó rán ọ láti wádìí nípa mi. ‘Àwọn ọmọ ogun Fáráò tó jáde láti kún ọ lọ́wọ́ yóò padà sílẹ̀ wọn sí Éjíbítì.

8. Nígbà náà ni àwọn ará Bábílónì yóò padà láti gbógun ti ìlú. Wọn yóò mú wọn nígbèkùn, wọn yóò sì fi iná jó ìlú náà kanlẹ̀.’

9. “Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí: Ẹ má ṣe tan ara yín jẹ ní èrò wí pé, ‘Àwọn ará Bábílónì yóò fi wá sílẹ̀ pẹ̀lú ìdánilójú;’ wọn kò ní ṣe bẹ́ẹ̀.

10. Kódà tó bá ṣe pé wọn yóò ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun Bábílónì tí ń gbógun tì yín àti àwọn tí ìjàǹbá ṣe, tí wọ́n ti fi sílẹ̀ ní ibùdó wọn; wọn yóò jáde láti jó ìlú náà kanlẹ̀.”

11. Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ogun Bábílónì ti kúrò ní Jérúsálẹ́mù nítorí àwọn ọmọ ogun Fáráò.

12. Jeremáyà múra láti fi ìlú náà sílẹ̀, láti lọ sí olú ìlú Bẹ́ńjámínì láti gba ẹ̀tọ́ rẹ̀ nínú ohun ìní láàrin àwọn ènìyàn tó wà níbẹ̀.

13. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé ẹnu-bodè Bẹ́ńjámínì, olórí àwọn olùṣọ́ tí orúkọ rẹ ń jẹ́ Íríjà ọmọ Ṣelemáyà ọmọ Hananáyà mú un, ó wí pé, “Ìwọ ń yapa sí àwọn ará Bábílónì.”

14. Jeremáyà sọ wí pé, “Èyí kì í ṣe òtítọ́! Èmi kò yapa sí àwọn ará Bábílónì.” Ṣùgbọ́n Íríjà kọ tí ikún sí i, dípò èyí a mú Jeremáyà, ó sì mú un lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ìjòyè.

Ka pipe ipin Jeremáyà 37