Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 37:4-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Nígbà yìí Jeremáyà sì ń wọlé, ó sì ń jáde láàrin àwọn ènìyàn nítorí wọ́n ti fi sínú túbú.

5. Àwọn ọmọ ogun Fáráò ti jáde kúrò nílẹ̀ Éjíbítì àti nígbà tí àwọn ará Bábílónì tó ń ṣàtìpó ní Jérúsálẹ́mù gbọ́ ìròyìn nípa wọn, wọ́n kúrò ní Jérúsálẹ́mù.

6. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Jeremáyà òjíṣẹ́ Ọlọ́run wá:

7. “Èyí ni, ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn Ísírẹ́lì sọ fún Ọba àwọn Júdà tó rán ọ láti wádìí nípa mi. ‘Àwọn ọmọ ogun Fáráò tó jáde láti kún ọ lọ́wọ́ yóò padà sílẹ̀ wọn sí Éjíbítì.

8. Nígbà náà ni àwọn ará Bábílónì yóò padà láti gbógun ti ìlú. Wọn yóò mú wọn nígbèkùn, wọn yóò sì fi iná jó ìlú náà kanlẹ̀.’

9. “Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí: Ẹ má ṣe tan ara yín jẹ ní èrò wí pé, ‘Àwọn ará Bábílónì yóò fi wá sílẹ̀ pẹ̀lú ìdánilójú;’ wọn kò ní ṣe bẹ́ẹ̀.

10. Kódà tó bá ṣe pé wọn yóò ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun Bábílónì tí ń gbógun tì yín àti àwọn tí ìjàǹbá ṣe, tí wọ́n ti fi sílẹ̀ ní ibùdó wọn; wọn yóò jáde láti jó ìlú náà kanlẹ̀.”

11. Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ogun Bábílónì ti kúrò ní Jérúsálẹ́mù nítorí àwọn ọmọ ogun Fáráò.

Ka pipe ipin Jeremáyà 37