Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 34:11-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, wọ́n yí ọkàn wọn padà; wọ́n sì mú àwọn ẹrú tí wọ́n ti dá sílẹ̀ padà láti tún máa sìn wọ́n.

12. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wá wí pé:

13. “Èyí ni ohun tí Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé: Mo dá májẹ̀mú kan pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín nígbà tí mo mú wọn kúrò ní Éjíbítì; kúrò ní oko ẹrú. Mo wí pé,

14. ‘Ní ọdún keje, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbọdọ̀ tú àwọn Hébérù tí wọ́n ti ta ara wọn fún un yín sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti sìn yín fún ọdún mẹ́fà. Ẹ gbọdọ̀ jẹ́ kí wọn kí ó lọ’; ṣùgbọ́n àwọn baba yín kò gbọ́; bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fetí sími.

15. Láìpẹ́ yìí ẹ ti ronúpìwàdà, ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú mi, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín sì ṣe ìtúsílẹ̀ fún àwọn ènìyàn. Ẹ sì tún bá mi dá májẹ̀mú ní àwọn ilé tí a ti ń pe orúkọ mi.

16. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin yípadà, ẹ sì sọ orúkọ mi di èérí, olúkúlùkù sì mú kí àwọn ẹni rẹ tí ó ti sọ di òmìnira bí ọkàn wọn ti fẹ́ padà; ẹ̀yin sì tún fi wọ́n ṣe ẹrú.

17. “Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí: Ẹ̀yin kò fetí sími nípa ọ̀rọ̀ òmìnira láàrin ẹ̀gbọ́n sí àbúrò, láàrin ẹnìkan sí èkejì rẹ̀. Wò ó, èmi yóò kéde òmìnira fún un yín ni Olúwa wí. Sí idà, sí àjàkálẹ̀-àrùn, àti sí ìyàn, èmi ó sì fi yín fún ìwọ̀sí ní gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé.

18. Èmi ó ṣe àwọn ọkùnrin náà tí ó da májẹ̀mú mi, tí kò tẹ̀lé májẹ̀mú tí wọ́n ti dá níwájú mi bí ẹgbọ̀rọ màlúù tí wọ́n gé sí méjì, tí ó sì kọjá láàrin ìpín méjì náà.

19. Àwọn ìjòyè Júdà àti àwọn ti Jérúsálẹ́mù, àwọn aláṣẹ àti àwọn àlùfáà àti gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà tí ó kọjá láàrin àwọn ìpín méjèèjì náà.

20. Èmi ó fi wọ́n lé ọwọ́ àwọn ọ̀ta wọn, àti lé àwọn tí ń wá ẹ̀mí wọn lọ́wọ́. Òkú wọn yóò jẹ́ oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti fún àwọn ẹranko ìgbẹ́.

Ka pipe ipin Jeremáyà 34