Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 32:36-44 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

36. “Ìwọ ń sọ̀rọ̀ nípa ti ìlú yìí pé, ‘Pẹ̀lú idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn ni à ó fi wọ́n fún Ọba Bábílónì,’ ṣùgbọ́n ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nì yìí:

37. Èmi ó kó wọn jọ láti gbogbo ilẹ̀ tí mo ti lé wọn kúrò ní ìgbà ìbínú àti ìkáàánú ńlá mi. Èmi yóò mú wọn padà wá sí ilẹ̀ yìí; èmi ó sì jẹ́ kí wọn ó máa gbé láìléwu.

38. Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.

39. Èmi ó fún wọn ní ọkàn kan àti ìṣe kí wọn kí ó lè máa bẹ̀rù mi fún rere wọn àti fún rere àwọn ọmọ wọn tí ó tẹ̀lé wọn.

40. Èmi ò bá wọn dá májẹ̀mú ayérayé, èmi kò ní dúró láti ṣe rere fún wọn: Èmi ó sì jẹ́ kí wọ́n bẹ̀rù mi, wọn kì yóò sì padà lẹ́yìn mi.

41. Èmi ó yọ̀ nípa ṣíṣe wọ́n ní rere, èmi ó sì fi dá wọn lójú nípa gbíngbìn wọ́n sí ilẹ̀ yìí tọkàntọkàn mi.

42. “Nítorí bayìí ni Olúwa wí: Gẹ́gẹ́ bí èmi ti mú gbogbo ibi ńlá yìí wá sórí àwọn ènìyàn yìí, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó mú gbogbo rere tí èmi ti sọ nípa ti wọn wá sórí wọn.

43. Lẹ́ẹ̀kan síi, pápá yóò di rírà ní ilẹ̀ yìí tí ìwọ ti sọ pé, ‘Ohun òfò ni tí kò bá sí ọkùnrin tàbí àwọn ẹran, nítorí tí a ti fi fún àwọn ará Bábílónì.’

44. Wọn ó fi owó fàdákà ra oko, wọn yóò fi ọwọ́ sí ìwé, wọn ó dí i pa pẹ̀lú ẹlẹ́rìí láti ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì àti ní ìlú kékèké tí ó yí Jérúsálẹ́mù ká àti ní ìlú Júdà àti ní ìlú ọwọ́ òkè orílẹ̀ èdè ní ìhà gúṣù olókè ilẹ̀ àti ní Gúsù, nítorí èmi ó mú ìgbékùn wọn padà wá, ni Olúwa wí.”

Ka pipe ipin Jeremáyà 32