Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 31:7-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ wí pé:“Ẹ fi ayọ̀ Kọrin sí Jákọ́bù;ẹ hó sí olórí àwọn orílẹ̀ èdè gbogbo.Jẹ́ kí wọ́n gbọ́ ìyìn rẹ kí o sì wí pé,‘Olúwa, gba àwọn ènìyàn rẹ là;àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Ísírẹ́lì.’

8. Wò ó, Èmi yóò mú wọn wá láti ilẹ̀ àríwá;èmi yóò kó gbogbo wọn jọ láti òpin ayé.Lára wọn ni yóò jẹ́ afọ́jú àti arọ,aboyún àti obìnrin tí ń rọbí,ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò wá.

9. Wọn yóò wá pẹ̀lú ẹkún,wọn yóò gbàdúrà bí Èmi yóò ṣe mú wọn padà.Èmi yóò jẹ́ atọ́nà fún wọn ní ẹ̀bá odò omi;ní ọ̀nà tí ó tẹ́jú tí wọn kì yóò le ṣubú,nítorí èmi ni baba Ísírẹ́lì,Éfúráímù sì ni àkọ́bí ọkùnrin mi.

10. “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin orílẹ̀ èdèẹ kéde rẹ̀ ní erékùsù jínjìn;‘Ẹni tí ó bá tú Ísírẹ́lì ká yóò kójọ,yóò sì ṣọ́ agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn.’

11. Nítorí Olúwa ti tú Jákọ́bù sílẹ̀, o sì ràá padàní ọwọ́ àwọn tí ó lágbára jù ú lọ

12. Wọn yóò wá, wọn ó sì hó ìhó ayọ̀ lórí òkè Síónì;wọn yóò yọ ayọ̀ níbi oore Olúwa.Àlìkámà ni, ọtí wáìnì tuntun àti òróróọ̀dọ́ àgùntàn àti ọ̀dọ́ ọ̀wọ́ ẹran.Wọn ó dàbí ọgbà àjàrà tí a bomirin,ìkorò kò ní bá wọn mọ́.

13. Àwọn wúndíá yóò jó, wọn ó sì kún fún ayọ̀,bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọkùnrin àti obìnrin.Èmi yóò sọ ọ̀fọ̀ wọn di ayọ̀,dípò ìkorò èmi yóò tù wọ́n nínú.Èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀.

14. Èmi ó tẹ́ àwọn àlùfáà lọ́rùn pẹ̀lú ọ̀pọ̀;àwọn ènìyàn mi yóò sì kún fún oore mi,”ni Olúwa wí.

15. Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“A gbọ́ ohùn kan ní Rámàtí ń sọ̀fọ̀ pẹ̀lú ẹkún kíkorò.Rákélì ń sọkún fún àwọn ọmọ rẹ̀;kò gbà kí wọ́n tu òun nínú,nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ kò sí mọ́.”

16. Báyìí ni Olúwa wí:“Dá ohùn rẹ dúró nínú ẹkúnàti ojú rẹ nínú omijé;nítorí a ó fi èrè sí isẹ́ rẹ,”ni Olúwa wí.“Wọn ó sì padà wá láti ilẹ̀ ọ̀tá.

17. Nítorí ìrètí wà fún ọjọ́ iwájú rẹ,”ni Olúwa wí.“Àwọn ọmọ rẹ yóò padà wá sí ilẹ̀ wọn.

18. “Nítòótọ́, èmi ti gbọ́ ìpohùnréré Éfúráímù wí pé,‘Ìwọ ti bá mi wí gẹ́gẹ́ bí ọmọ màlúù tí a kò kọ́èmi sì ti gbọ́ ìbáwí.Ràmípadà, Èmi yóò sì yípadà,nítorí ìwọ ni Olúwa Ọlọ́run mi.

19. Lẹ́yìn tí mo ti ronúpìwàdà,èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi,lẹ́yìn tí mo ti mọ̀,èmi lu àyà mi.Ojú tì mí, mo sì dààmú;nítorí èmi gba èrè ẹ̀gàn ìgbà èwe mi.’

Ka pipe ipin Jeremáyà 31