Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 31:31-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. “Ìgbà kan ń bọ̀,” ni Olúwa wí,“tí Èmi yóò bá ilé Ísírẹ́lì àtiilé Júdà dá májẹ̀mú tuntun.

32. Kò ní dàbí májẹ̀mútí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá,nígbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́,tí mo mú wọn jáde ní Éjíbítìnítorí wọ́n da májẹ̀mú mi.Lóòótọ́ ọkọ ni èmi jẹ́ fún wọn,”ni Olúwa wí.

33. “Èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Ísírẹ́lì dálẹ́yìn ìgbà náà,” ni Olúwa wí pé:“Èmi yóò fi òfin mi sí ọkàn wọn,èmi ó sì kọ ọ́ sí àyà wọn.Èmi ó jẹ́ Olúwa wọn;àwọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi.

34. Kò ní sí pé ọkùnrin kan ń kọ́ àwọn ará ilé rẹ̀tàbí ọkùnrin ń kọ́ arákùnrin rẹ̀ pé, ‘Ẹ mọ Olúwa,’nítorí gbogbo wọn ni yóò mọ̀ míláti ẹni kékeré wọn títídé ẹni ńlá,”ni Olúwa wí.“Nítorí èmi ó dárí àìṣedédé wọn jì,èmi kò sì ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.”

35. Èyí ni ohun tí Olúwa wí:ẹni tí ó mú oòrùntan ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán,tí ó mú òṣùpá àti ìràwọ̀ràn ní òru;tí ó rú omi òkun sókètó bẹ́ẹ̀ tí Ìjì rẹ̀ fi ń hó Olúwa àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.

Ka pipe ipin Jeremáyà 31