Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 31:26-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Lórí èyí ni mo jí, mo sì wò yíká, oorun mi sì dùn mọ́ mi.

27. “Wò ó, ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “nígbà tí èmi yóò gbin ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà pẹ̀lú irúgbìn ọmọ ènìyàn àti ẹranko.

28. Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń ṣọ́ wọn, láti fàtu, àti láti wó lulẹ̀, àti láti gba ìṣàkóso, láti bàjẹ́ àti láti mú ibi wá, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣọ́ wọn láti kọ́ àti láti gbìn,” ni Olúwa wí.

29. “Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àwọn ènìyàn kò ní sọ mọ́ pé:“ ‘Àwọn baba ti jẹ èṣo kíkanàti pé ẹyín kan àwọn ọmọdé.’

30. Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ni yóò kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ èṣo kíkan ni eyín yóò kan.

31. “Ìgbà kan ń bọ̀,” ni Olúwa wí,“tí Èmi yóò bá ilé Ísírẹ́lì àtiilé Júdà dá májẹ̀mú tuntun.

32. Kò ní dàbí májẹ̀mútí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá,nígbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́,tí mo mú wọn jáde ní Éjíbítìnítorí wọ́n da májẹ̀mú mi.Lóòótọ́ ọkọ ni èmi jẹ́ fún wọn,”ni Olúwa wí.

33. “Èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Ísírẹ́lì dálẹ́yìn ìgbà náà,” ni Olúwa wí pé:“Èmi yóò fi òfin mi sí ọkàn wọn,èmi ó sì kọ ọ́ sí àyà wọn.Èmi ó jẹ́ Olúwa wọn;àwọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi.

34. Kò ní sí pé ọkùnrin kan ń kọ́ àwọn ará ilé rẹ̀tàbí ọkùnrin ń kọ́ arákùnrin rẹ̀ pé, ‘Ẹ mọ Olúwa,’nítorí gbogbo wọn ni yóò mọ̀ míláti ẹni kékeré wọn títídé ẹni ńlá,”ni Olúwa wí.“Nítorí èmi ó dárí àìṣedédé wọn jì,èmi kò sì ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.”

35. Èyí ni ohun tí Olúwa wí:ẹni tí ó mú oòrùntan ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán,tí ó mú òṣùpá àti ìràwọ̀ràn ní òru;tí ó rú omi òkun sókètó bẹ́ẹ̀ tí Ìjì rẹ̀ fi ń hó Olúwa àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.

36. “Àyàfi tí ìlànà yìí bá kúrò níwájú mi,”ni Olúwa wí.“Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò dẹ́kunláti jẹ́ orílẹ̀ èdè níwájú mi láéláé.”

37. Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“Àyàfi tí a bá lé àwọn ọ̀run lókètí ìpìlẹ̀ ayé sì di àwárí ní ìṣàlẹ̀,ni èmi yóò kọ àwọn Ísírẹ́lìnítorí ohun gbogbo tí wọ́n ti ṣe,”ni Olúwa wí.

38. “Ọjọ́ náà ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí wọn yóò tún ìlú yìí kọ́ fún mi láti ilé ìṣọ́ Hánánélì dé igun ẹnubodè.

39. Okùn ìwọ̀n yóò sì nà jáde láti ibi gígùn lọ sí òkè Gárébì yóò sì lọ sí Góà.

Ka pipe ipin Jeremáyà 31