Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 31:20-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Éfúráímù kì í ha í ṣe ọmọkùnrin mi dáradáratí inú mi dùn sí bí?Bí èmi ti ń sọ̀rọ̀ sí i tó,síbẹ̀, èmi rántí rẹ̀.Nítorí náà, ọkàn mi ṣe ohun kan fún un,èmi káàánú gidigidi fún un,”ni Olúwa wí.

21. “Gbé àmì ojú ọ̀nà dìde,ṣe atọ́nà àmì,kíyèsí pópónà rélùwéèojú ọ̀nà tí ó ń gbà.Yípadà ìwọ wúndíá Ísírẹ́lì,padà sí àwọn ìlú rẹ.

22. Ìwọ yóò ti sìnà pẹ́ tó,ìwọ aláìsòótọ́ ọmọbìnrin; Olúwa yóò dá ohun tuntun lórí ilẹ̀,ọmọbìnrin yóò yí ọkùnrin kan ká.”

23. Báyìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì wí: “Nígbà tí èmi bá kó wọn dé láti ìgbèkùn; àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ Júdà àti ní àwọn ìlú rẹ̀ yóò tún lo àwọn ọ̀rọ̀ yìí lẹ́ẹ̀kan síi; wí pé, ‘Olúwa bùkún fún ọ, ìwọ tí ń gbé nínú òdodo, ìwọ òkè ìwà mímọ́.’

24. Àwọn ènìyàn yóò gbé papọ̀ ní Júdà àti ní gbogbo àwọn ìlú rẹ̀; bákan náà ni àgbẹ̀ àti àwọn tí ń tẹ̀lé agbo ẹran wọn ká.

25. Èmi yóò sọ aláàárẹ̀ di ọ̀tun, èmi yóò sì tẹ́ gbogbo ọkàn tí ń káànú lọ́rùn.”

26. Lórí èyí ni mo jí, mo sì wò yíká, oorun mi sì dùn mọ́ mi.

27. “Wò ó, ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “nígbà tí èmi yóò gbin ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà pẹ̀lú irúgbìn ọmọ ènìyàn àti ẹranko.

28. Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń ṣọ́ wọn, láti fàtu, àti láti wó lulẹ̀, àti láti gba ìṣàkóso, láti bàjẹ́ àti láti mú ibi wá, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣọ́ wọn láti kọ́ àti láti gbìn,” ni Olúwa wí.

Ka pipe ipin Jeremáyà 31