Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 30:16-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. “ ‘Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe yín ní ibi ni ibi yóò bá,àní gbogbo àwọn ọ̀ta yín ni a ó sọ di àtìpó ní ilẹ̀ àjòjì;gbogbo àwọn tí wọ́n bà yín jẹ́ ni a ó bàjẹ́.

17. Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìlera fún yín,n ó sì wo ọ̀gbẹ́ yín sàn,’ni Olúwa wí,‘nítorí tí a pè yín ní alárìnkiriSíónì tí gbogbo ènìyàn dágunlá sí.’

18. “Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“ ‘Èmi yóò dá gbogbo ire àgọ́ Jákọ́bù padà,èmi yóò sì ṣe àánú fún olùgbé àgọ́ rẹ̀;ìlú náà yóò sì di títúnṣetí ààfin ìlú náà yóò sì wà ní ipò rẹ̀.

19. Láti ẹnu wọn ni orin ọpẹ́ àtiìyìn yóò sì ti máa jáde.Èmi yóò sọ wọ́n di púpọ̀,wọn kì yóò sì dínkù ní iye,Èmi yóò fi ọlá fún wọn,wọn kò sì ní di ẹni àbùkù.

20. Ọmọ ọmọ wọn yóò wà bí i ti ìgbàanìníwájú mi ni wọn yóò sì tẹ àwùjọ wọn dúró sí.Gbogbo ẹni tó bá ni wọ́n lára,ni èmi yóò fìyà jẹ.

21. Ọ̀kan nínú wọn ni yóò jẹ́ olórí wọn,Ọba wọn yóò dìde láti àárin wọn.Èmi yóò mú un wá sí ọ̀dọ̀ mi, òun yóò sì súnmọ́ mi,nítorí ta ni ẹni náà tí yóò fi ara rẹ̀ jìn láti súnmọ́ mi?

22. Nítorí náà, ẹ̀yin yóò jẹ́ ènìyàn mi,èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín,’ ”ni Olúwa wí.

23. Wò ó, ìbínú Ọlọ́run yóò tú jáde,ìjì líle yóò sì sọ̀kalẹ̀ sórí àwọn ènìyàn búburú.

24. Ìbínú ńlá Ọlọ́run kò ní dẹ̀yìn lẹ́yìnàwọn ìkà títí yóò fi múèròǹgbà ọkàn rẹ̀ ṣẹ.Ní àìpẹ́ ọjọ́,òye rẹ̀ yóò yé e yín.

Ka pipe ipin Jeremáyà 30