Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 3:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Bí ọkùnrin kan bá sì kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀tí obìnrin náà sì lọ fẹ́ ọkọ mìíràn,ǹjẹ́ ọkùnrin náà tún lè tọ̀ ọ́ wá?Ǹjẹ́ ilẹ̀ náà kò ní di aláìmọ́ bí?Ṣùgbọ́n ìwọ ti gbé pẹ̀lú onírúurú panṣágà gẹ́gẹ́ bí olùfẹ́,ṣé ìwọ yóò tún padà sọ́dọ̀ mi bí?”ni Olúwa wí.

2. “Gbé ojú rẹ sí ibi gíga aláìléso kí o sì wò óibi kan ha wà tí a kò ti fi agbára mú ọ?Ní ojú ọ̀nà, ìwọ jókòó de àwọn olólùfẹ́,o jókòó bí i àwọn alárìnkiri nínú ihà.O ti ba ilẹ̀ náà jẹ́pẹ̀lú ìwà panṣágà àti ìwà búburú rẹ.

3. Nítorí náà, a ti fa ọ̀wàrà òjò sẹ́yìn,kò sì sí òjò àrọ̀kúrò.Síbẹ̀ ìwọ ní ojú líle ti panṣágà,ìwọ sì kọ̀ láti ní ìtìjú.

4. Ǹjẹ́ ìwọ kò há a pè mí láìpẹ́ yìí pé,‘Baba mi, ìwọ ọ̀rẹ́ mi láti ìgbà èwe mi.

5. Ìwọ yóò ha máa bínú títí?Ìbínú rẹ yóò ha máa lọ títí láé?’Báyìí ni o ṣe ń sọ̀rọ̀ìwọ ń ṣe gbogbo ibi tí o le ṣe.”

6. Ní àkókò ìjọba Jòsáyà Ọba, Olúwa wí fún mi pé, “Ṣé o ti rí nǹkan tí àwọn Ísírẹ́lì aláìnígbàgbọ́ ti ṣe? Wọ́n ti lọ sí àwọn òkè gíga àti sí abẹ́ àwọn igi, wọ́n sì ti ṣe àgbèrè níbẹ̀.

7. Mo rò pé nígbà tí wọ́n ti ṣe èyí wọn yóò padà, wọn kò padà, Júdà aláìgbàgbọ́ arábìnrin rẹ̀ náà sì rí i.

8. Mo fún Ísírẹ́lì aláìnígbàgbọ́ ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀, mo sì ké wọn kúrò nítorí gbogbo àgbèrè wọn. Ṣíbẹ̀ mo rí pé Júdà tí ó jẹ́ arábìnrin rẹ̀ kò bẹ̀rù, òun náà sì jáde lọ láti lọ ṣe àgbèrè.

9. Nítorí ìwà èérí Ísírẹ́lì kò jọ ọ́ lójú, ó ti ba ilẹ̀ jẹ́, ó sì ti ṣe àgbèrè pẹ̀lú òkúta àti igi.

10. Látàrí gbogbo nǹkan wọ̀nyí Júdà arábìnrin rẹ̀ aláìgbàgbọ́ kò padà tọ̀ mí wá pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀, bí kò ṣe nípa fífarahàn bí olótìtọ́,” ni Olúwa wí.

11. Olúwa wí fún mi pé, “Ísírẹ́lì aláìnígbàgbọ́ ṣe òdodo ju Júdà tí ó ní Ìgbàgbọ́ lọ.

12. Lọ polongo ọ̀rọ̀ náà, lọ sí ìhà àríwá:“ ‘Yípadà, Ísírẹ́lì aláìnígbàgbọ́,’ ni Olúwa wí.‘Ojú mi kì yóò le sí yín mọ́,nítorí mo jẹ́ aláàánú, ni Olúwa wí.

13. Sá à ti mọ ẹ̀bi rẹ,o ti ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ,o ti wá ojú rere rẹ lọ́dọ̀ ọlọ́run àjèjìlábẹ́ gbogbo igikígi,tí ó tẹ́wọ́, o kò sì gbọ́ràn sí mi lẹ́nu,’ ”ni Olúwa wí.

14. “Padà, ẹ̀yin ènìyàn aláìnígbàgbọ́,” ni Olúwa wí, “nítorí èmi ni ọkọ rẹ. Èmi ó yàn ọ́, ọ̀kan láti ìlú àti méjì láti ẹ̀yà. Èmi ó sì mú ọ wá sí Síónì.

Ka pipe ipin Jeremáyà 3