Ní àkókò ìjọba Jòsáyà Ọba, Olúwa wí fún mi pé, “Ṣé o ti rí nǹkan tí àwọn Ísírẹ́lì aláìnígbàgbọ́ ti ṣe? Wọ́n ti lọ sí àwọn òkè gíga àti sí abẹ́ àwọn igi, wọ́n sì ti ṣe àgbèrè níbẹ̀.