Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 29:25-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run alágbára Ísírẹ́lì wí: Ìwọ fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ènìyàn ní Jérúsálẹ́mù sí Sefanáyà ọmọ Mááséà tí í ṣe àlùfáà ní orúkọ mi; ó sì sọ fún Sefanáyà wí pé,

26. ‘Olúwa ti yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà rọ́pò Jéhóíádà láti máa jẹ́ alákóso ilé Olúwa, kí o máa fi èyíkéyìí nínú àwọn aṣiwèrè tó bá ṣe bí i wòlíì si inú àgò irin.

27. Nítorí náà, èéṣe tí o kò fi bá Jeremáyà ará Ánátótì wí. Ẹni tí ó ń dúró bí i wòlíì láàrin yín?

28. Ó ti rán iṣẹ́ yìí sí wa ni Bábílónì wí pé, àtìpó náà yóò pẹ́ kí ó tó parí, nítorí náà, ẹ kọ́ ilé kí ẹ sì máa gbé ibẹ̀, ẹ dá oko, kí ẹ sì máa jẹ èṣo ohun ọ̀gbìn oko yín.’ ”

29. Sefanáyà àlùfáà ka lẹ́tà náà sí etí ìgbọ́ Jérúsálẹ́mù tí í ṣe wòlíì.

30. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wá wí pé,

31. “Rán iṣẹ́ yìí sí gbogbo àwọn àtìpó: ‘Èyí ni ohun tí Olúwa sọ nípa Ṣemáyà àti Neelamaiti: Nítorí pé Semaíà ti sọ tẹ́lẹ̀ fún un yín, súgbọ́n èmi kò ran an, tí òun sì ń mú u yín gbẹ́kẹ̀lé èké.

32. Nítorí pé, Èmi kò rán Ṣemáyà ní àṣọtẹ́lẹ̀ tí ó sọ fún un yín, ó sì ti mú kí ẹ gba àṣọtẹ́lẹ̀ èké gbọ́. Èmi yóò fi ìyà jẹ Ṣemáyà àti àwọn ọmọ rẹ̀. Kò sí ẹni tí yóò ṣẹ́kù nínú àwọn ìran rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò rí àwọn ohun rere tí èmi yóò ṣe fún àwọn ènìyàn mi, nítorí ó ti kéde ìṣọ̀tẹ̀ sí mi, ni Olúwa wí.’ ”

Ka pipe ipin Jeremáyà 29