Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 25:28-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Ṣùgbọ́n bí wọ́n ba kọ̀ láti gba aago náà ní ọwọ́ rẹ kí wọ́n sì mu ún, sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Ọlọ́run alágbára sọ: Ẹyin gbọdọ̀ mu ún!

29. Wò ó, èmi ń mú ibi bọ̀ sí orí orílẹ̀ èdè tí ó ń jẹ́ orúkọ mi; ǹjẹ́ yóò há a lè lọ láìjìyà? Ẹ̀yin ń pe idà sọ̀kalẹ̀ sórí gbogbo àwọn olùgbé ayé, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ.’

30. “Nísinsinyìí, sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nípa wọn:“ ‘Kí o sì sọ pé, Olúwa yóò bú láti òkè wá,yóò sì bú àrá kíkankíkan sí ilẹ̀ náà.Yóò parí gbogbo olùgbé ayé, bí àwọn tí ń tẹ ìfúntí

31. Ìrọ́kẹ̀kẹ̀ yóò wà títí dé òpin ilẹ̀ ayé,nítorí pé Olúwa yóò mú ìjà wá sí oríàwọn orílẹ̀ èdè náà,yóò mú ìdájọ́ wá sórí gbogbo ènìyàn,yóò sì fi àwọn olùṣe búburú fún idà,’ ”ni Olúwa wí.

32. Èyí ni ohun tí Olúwa ọmọ ogun wí:“Wò ó! Ibi ń tànkálẹ̀ láti orílẹ̀ èdè kan sí òmíràn;Ìjì ńlá yóò sì ru sókè láti òpin ayé.”

33. Nígbà náà, àwọn tí Olúwa ti pa yóò wà ní ibi gbogbo, láti ìpẹ̀kun kan sí òmíràn. A kì yóò sọ̀fọ̀ wọn, a kì yóò kó wọn jọ tàbí sin wọ́n; ṣùgbọ́n wọn yóò dàbí ààtàn lórí ilẹ̀.

34. Ké, kí ẹ sì pohùnréré ẹkúnẹ̀yin olùsọ́ àgùntàn, ẹ yí nínú eruku,ẹ̀yin olùdarí agbo ẹran,nítorí pé ọjọ́ àti pa yín ti dé,ẹ̀yin ó sì ṣubú bí ohun èlò iyebíye.

35. Àwọn olùsọ́ àgùntàn kì yóò ríbi sálọkì yóò sì sí àsálà fún olórí agbo ẹran.

36. Gbọ́ igbe àwọn olùsọ́ àgùntàn,àti ìpohùnréré ẹkún àwọn olóríagbo ẹran; nítorí pé Olúwa ń pa pápá oko tútù wọn run.

37. Pápá oko tútù yóò di asánnítorí ìbínú ńlá Olúwa.

38. Gẹ́gẹ́ bí kìnnìún yóò fi ibùba rẹ̀ sílẹ̀,ilẹ̀ wọn yóò sì di ahoro, nítorí idà àwọn anínilára,àti nítorí ìbínú ńlá Olúwa.

Ka pipe ipin Jeremáyà 25