Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 24:4-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:

5. “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: ‘Gẹ́gẹ́ bí àwọn èṣo ọ̀pọ̀tọ́ dáradára yìí ni Èmi yóò ka àwọn tí wọ́n lọ sí ilẹ̀ àjòjì láti Júdà sí tí èmi rán jáde kúrò ní ibí yìí lọ sí ilẹ̀ àwọn ará kálídéà

6. Ojú mi yóò máa ṣọ́ wọn lọ fún rere; Èmi yóò gbé wọn ró, n kò ní já wọn lulẹ̀. Èmi yóò gbìn wọ́n, n kò sì ní fà wọ́n tu.

7. Èmi yóò fún wọn ní ọkàn láti mọ̀ mí pé, Èmi ni Olúwa. Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi; Èmi ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn; nítorí pé wọn yóò padà sọ́dọ̀ mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn.

8. “ ‘Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí èṣo ọ̀pọ̀tọ́ tí kò dára, tí ó burú tí kò ṣe é jẹ,’ ni Olúwa wí, ‘bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò ṣe pẹ̀lú Ṣedekáyà Ọba Júdà, àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn tí ó yẹ ní Jérúsálẹ́mù, yálà wọ́n wà lórí ilẹ̀ yìí tàbí wọ́n ń gbé Éjíbítì.

9. Èmi yóò sọ wọ́n di ìwọ̀sí àti ẹni ibi sí gbogbo ìjọba ayé, ẹni ẹ̀sín àti ẹni ẹ̀tẹ́, ẹni àbùkù àti ẹni èpè ní ibi gbogbo tí Èmi bá lé wọn sí.

10. Èmi yóò rán idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn sí wọn, títí tí gbogbo wọn yóò parun lórí ilẹ̀ tí a fún wọn àti fún àwọn baba wọn.’ ”

Ka pipe ipin Jeremáyà 24