Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 23:9-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Nípa ti àwọn wòlíì èké:Ọkàn mi ti bàjẹ́ nínú mi,gbogbo egungun mi ni ó wárìrì.Èmi dàbí ọ̀mùtí ènìyàn,bí ọkùnrin tí ọtí wáìnì ń pa;nítorí Olúwa àti àwọn ọ̀rọ̀ mímọ́ rẹ̀.

10. Ilẹ̀ náà kún fún panṣágà ènìyànnítorí ẹ̀gún ilẹ̀ náà gbẹ,àwọn kóríko orí aṣálẹ̀ ilẹ̀ náà rọ.Àwọn wòlíì tẹ̀lé ọ̀nà búburú,wọ́n sì ń lo agbára wọn lọ́nà àìtọ́.

11. “Wòlíì àti àlùfáà kò gbé ìgbé ayé ìwàbí Ọlọ́run;kódà nínú Tẹ́ḿpìlì mi ni mo rí ìwà búburú wọn,”ni Olúwa wí.

12. “Nítorí náà, ọ̀nà wọn yóò di yíyọ́,a ó lé wọn jáde sínú òkùnkùn;níbẹ̀ ni wọn yóò ṣubú.Èmi yóò mú ìdààmú wá sórí wọn,ní ọdún tí a jẹ wọ́n níyà,”ni Olúwa wí.

13. “Láàrin àwọn wòlíì Saáríà,Èmi rí ohun tí ń lé ni sá:Wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórúkọ Báálìwọ́n sì mú Ísírẹ́lì ènìyàn mi sìnà.

14. Àti láàrin àwọn wòlíì Jérúsálẹ́mù,èmi ti rí ohun búburú:Wọ́n ṣe panṣágà, wọ́n sì ń ṣèké.Wọ́n fún àwọn olùṣe búburú ní agbára,tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí ẹnìkan tí ó yípadà kúrò nínú ìwà búburú rẹ̀.Gbogbo wọn dàbí Sódómù níwájú mi,àti àwọn ènìyàn olùgbé rẹ̀ bí Gòmórà.”

15. Nítorí náà, báyìí ni OlúwaỌlọ́run alágbára wí ní ti àwọn wòlíì:“Èmi yóò mú wọn jẹ oúnjẹ kíkorò,wọn yóò mu omi májèlénítorí láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì Jérúsálẹ́mùni àìwà-bí-Ọlọ́run ti tàn ká gbogbo ilẹ̀.”

Ka pipe ipin Jeremáyà 23