Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 22:21-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Èmi ti kìlọ̀ fún ọ nígbà tí o rò pé kò séwu,ṣùgbọ́n o sọ pé, ‘Èmi kì yóò fetísílẹ̀!’Èyí ni iṣẹ́ rẹ láti ìgbà èwe rẹ,ìwọ kò fìgbà kan gba ohùn mi gbọ́.

22. Ẹ̀fúùfù yóò lé gbogbo àwọn olùṣọ́-àgùntàn rẹ̀ lọ,gbogbo àwọn olùfẹ́ rẹ yóò lọ sí ìgbékùn,nígbà náà ni a ó kẹ́gàn rẹ, ojú yóò tì ọ́nítorí gbogbo ìwà búburú rẹ.

23. Ìwọ tí ń gbé ‘Lẹ́bánónì,’tí ó tẹ́ ìtẹ́ sí orí igi kédárì,ìwọ yóò ti kérora pẹ́ tó, nígbà tí ìrora bá dé bá ọ,ìrora bí i ti obìnrin tí ń rọbí!

24. “Dájúdájú bí èmi ti wà láàyè,” ni Olúwa wí, “Bí Jéhóíákínì ọmọ Jéhóíákímù Ọba Júdà tilẹ̀ jẹ́ òrùka èdìdì lọ́wọ́ ọ̀tún mi, síbẹ̀ èmi ó fà ọ́ tu kúrò níbẹ̀.

25. Èmi ó sì fà ọ́ lé ọwọ́ àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí rẹ, àwọn tí ìwọ bẹ̀rù, àní lé ọwọ́ Nebukadinésárì, Ọba Bábílónì àti ọwọ́ àwọn ará Bábílónì.

26. Èmi ó fi ìwọ àti ìyá tí ó bí ọ sọ̀kò sí ilẹ̀ mìíràn, níbi tí a kò bí ẹnikẹ́ni nínú yín sí. Níbẹ̀ ni ẹ̀yin méjèèjì yóò kú sí.

27. Ẹ̀yin kì yóò padà sí ilẹ̀ tí ẹ̀yin fẹ́ mọ́ láéláé.”

28. Ǹjẹ́ Jéhóíákínì ẹni ẹ̀gàn yàtọ̀ sí ìkòkò òfìfo,ohun èlò tí ẹnìkan kò fẹ́?Èéṣe tí a fi òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ sókèsí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.

Ka pipe ipin Jeremáyà 22