Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 22:18-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí, nípa Jehóíákímù ọmọ Jòsáyà, Ọba Júdà:“Wọn kì yóò ṣọ̀fọ̀ fún un:wí pé, ‘Ó ṣe, arákùnrin mi! Ó ṣe, arábìnrin mi!’Wọn kì yóò sọ̀fọ̀ fún un:wí pé, ‘Ó ṣe, olúwa tàbí ó ṣe kábíyèsí!’

19. A ó sin òkú rẹ̀ bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́tí a wọ́ sọnù gba ti ẹnubodèJérúsálẹ́mù.”

20. “Gòkè lọ sí Lẹ́bánónì, kígbe sítakí a sì gbọ́ ohùn rẹ ní Básánì,kí o kígbe sókè láti Ábárímù,nítorí a ti run gbogbo àwọn olùfẹ́ rẹ túútúú.

21. Èmi ti kìlọ̀ fún ọ nígbà tí o rò pé kò séwu,ṣùgbọ́n o sọ pé, ‘Èmi kì yóò fetísílẹ̀!’Èyí ni iṣẹ́ rẹ láti ìgbà èwe rẹ,ìwọ kò fìgbà kan gba ohùn mi gbọ́.

22. Ẹ̀fúùfù yóò lé gbogbo àwọn olùṣọ́-àgùntàn rẹ̀ lọ,gbogbo àwọn olùfẹ́ rẹ yóò lọ sí ìgbékùn,nígbà náà ni a ó kẹ́gàn rẹ, ojú yóò tì ọ́nítorí gbogbo ìwà búburú rẹ.

23. Ìwọ tí ń gbé ‘Lẹ́bánónì,’tí ó tẹ́ ìtẹ́ sí orí igi kédárì,ìwọ yóò ti kérora pẹ́ tó, nígbà tí ìrora bá dé bá ọ,ìrora bí i ti obìnrin tí ń rọbí!

24. “Dájúdájú bí èmi ti wà láàyè,” ni Olúwa wí, “Bí Jéhóíákínì ọmọ Jéhóíákímù Ọba Júdà tilẹ̀ jẹ́ òrùka èdìdì lọ́wọ́ ọ̀tún mi, síbẹ̀ èmi ó fà ọ́ tu kúrò níbẹ̀.

25. Èmi ó sì fà ọ́ lé ọwọ́ àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí rẹ, àwọn tí ìwọ bẹ̀rù, àní lé ọwọ́ Nebukadinésárì, Ọba Bábílónì àti ọwọ́ àwọn ará Bábílónì.

Ka pipe ipin Jeremáyà 22