Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 22:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Báyìí ni Olúwa wí, “Sọ̀kalẹ̀ lọ sí ààfin Ọba Júdà, kí o sì sọ ọ̀rọ̀ yìí níbẹ̀:

2. ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ìwọ Ọba Júdà, tí ó jókòó ní Ìtẹ́ Dáfídì, ìwọ, àwọn ènìyàn rẹ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ, tí ó wọlé láti ẹnu ibodè wọ̀nyí.

3. Báyìí ni Olúwa wí: Ṣé ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ tí ó sì yẹ, kí o sì gba ẹni tí a fi ẹ̀tọ́ rẹ̀ dù ú kúrò lọ́wọ́ aninilára. Má ṣe hu ìwà ìpanilára, tàbí opó, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ níbí yìí.

4. Nítorí bí ẹ̀yin bá tẹ̀lé àṣẹ wọ̀nyí, nígbà náà ni àwọn Ọba inú ààfin láti ẹnu ọ̀nà, wọn yóò gun kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin, àwọn àti ìránṣẹ́ wọn àti àwọn ènìyàn wọn.

5. “Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá tẹ̀lé àṣẹ wọ̀nyí, mo búra fúnra mi pé ààfin yìí yóò di ìparun ni Olúwa wí.’ ”

6. Nítorí báyìí ni Olúwa wí, nípa ààfin Ọba Júdà,“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ dàbí Gílíádì sí mi,gẹ́gẹ́ bí góńgó òkè Lẹ́bánónì,dájúdájú Èmi yóò sọ ọ́ di aṣálẹ̀,àní gẹ́gẹ́ bí ìlú tí a kò gbé inú wọn.

7. Èmi ó rán apanirun sí ọolúkúlùkù ọkùnrin pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀,wọn yóò sì gé àsànyàn igi kédárì rẹ lulẹ̀,wọn ó sì kó wọn jù sínú iná.

8. “Àwọn ènìyàn láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè yóò rékọjá lẹ́bàá ìlú yìí wọn yóò sì máa bi ara wọn léèrè pé, ‘Èéṣe tí Olúwa ṣe irú èyí sí ìlú ńlá yìí?’

9. Ìdáhùn wọn yóò sì jẹ́: ‘Nítorí tí wọ́n ti kọ májẹ̀mú Olúwa Ọlọ́run wọn sílẹ̀, wọn ti ń fi oríbalẹ̀ fún Ọlọ́run mìíràn, wọ́n sì sìn wọ́n.’ ”

Ka pipe ipin Jeremáyà 22