Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 20:10-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Mo gbọ́ sísọ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́,ìbẹ̀rù ni ibi gbogboFi í sùn! Jẹ́ kí a fi sùn!Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ń dúrókí èmi ṣubú, wọ́n sì ń sọ pé,Bóyá yóò jẹ́ di títàn,nígbà náà ni àwa yóò borí rẹ̀,àwa yóò sì gba ẹ̀san wa lára rẹ̀.”

11. Ṣùgbọ́n Olúwa wà pẹ̀lú mi gẹ́gẹ́ bí jagunjagun alágbára.Nítorí náà, àwọn tí ó ń lépa mi yóò kọsẹ̀,wọn kì yóò sì borí.Wọn yóò kùnà, wọn yóò sì gba ìtìjú púpọ̀.Àbùkù wọn kì yóò sì di ohun ìgbàgbé.

12. Olúwa alágbára, ìwọ tí ó ń dán olódodo pípé wòtí o sì ń ṣe àyẹ̀wò ọkàn àti ẹ̀yà fínní-fínní,jẹ́ kí èmi kí ó rí ìgbẹ̀san rẹ lórí wọn,nítorí ìwọ ni mo gbé ara mi lé.

13. Kọrin sí Olúwa!Fi ìyìn fún Olúwa!Ó gba ẹ̀mí àwọn aláìnílọ́wọ́ àwọn ẹni búburú.

14. Ègbé ni fún ọjọ́ tí a bí mi!Kí ọjọ́ tí ìyá mi bí mi má ṣe di ti ìbùkún.

15. Ègbé ni fún ọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún baba mi,Tí ó mú kí ó yọ̀, tí ó sì sọ wí pé,“A bí ọmọ kan fún ọ—ọmọkùnrin!”

16. Kí ọkùnrin náà dàbí ìlútí Olúwa gbàkóso lọ́wọ́ rẹ̀ láìkáànúKí o sì gbọ́ ariwo ọ̀fọ̀ ní àárọ̀,ariwo ogun ní ọ̀sán.

Ka pipe ipin Jeremáyà 20