Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 2:14-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Ísírẹ́lì há á jẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀ẹrú nípa ìbí? Kí ló há adé tí ó fi di ìkógun?

15. Àwọn kìnnìún ké ramúramúwọ́n sì ń bú mọ́ wọnwọ́n ti fi ilẹ̀ rẹ̀ ṣòfòÌlú rẹ̀ ti di jíjóná, ó sìti di ìkọ̀sílẹ̀.

16. Bákan náà, àwọn ọkùnrinMémífísì àti Táfánésìwọ́n ti fa adé orí rẹ yọ.

17. Ẹ̀yin kò há a ti fa èyí sóríara yín nípa kíkọ Ọlọ́run sílẹ̀nígbà tí ó tọ́ ọ lójú ọ̀nà?

18. Kí ló dé tí o ṣe wá lọ Éjíbítìláti lọ mu omi ní Síhórì?Kí ló dé tí o sì fi lọ sí Àsíríàláti lọ mu omi ni odò Yúfúrátè náà

19. Iṣẹ́ búburú yín yóò fìyà jẹ yínÌpàdàṣẹ́yìn rẹ yóò sì bá ọ wímọ̀ kí o sì ríi wí pé ibi àtiohun búburú yóò sì jẹ́ tìrẹnígbà tí o ti kọ Ọlọ́run ọmọogun sílẹ̀, ẹ kò sì ní ìbẹ̀rù fún mi,”ni Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ ogun wí.

20. “Nígbà àtijọ́, o ti fọ́ àjàgàrẹ sọnù, ìwọ sì já ìdè rẹìwọ wí pé, ‘Èmi kì yóò sìn ọ́!’Lóòtọ́, lórí gbogbo òkè gíga niàti lábẹ́ igi tí ó tàn kálẹ̀ni ìwọ dùbúlẹ̀ sí gẹ́gẹ́ bí panṣágà.

21. Èmi ti gbìn ọ́ gẹ́gẹ́ bíàjàrà ọ̀tọ̀, gẹ́gẹ́ bí ìṣúra ọlọ́lá,Báwo wá ni ìwọ ṣe yípadà sí midi àjàrà búburú àti aláìmọ́?

22. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o wẹ ara rẹ pẹ̀lú sódàtí o sì lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọṣẹàbàwọ́n àìṣedéédéé rẹ sì ń bọ̀ níwájú mi,”ni Olúwa Àwọn ọmọ ogun wí.

Ka pipe ipin Jeremáyà 2