Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 18:3-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Nígbà náà ni mo lọ sí ilé amọ̀kòkò mo sì rí i tí ó ń ṣiṣẹ́ kan lórí kẹ̀kẹ́.

4. Ṣùgbọ́n ìkòkò tí ó ń mọ láti ara amọ̀ bàjẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀, nítorí náà ni amọ̀kòkò fi ṣe ìkòkò mìíràn, ó mọ ọ́n bí èyí tí ó dára jù ní ojú rẹ̀.

5. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé:

6. “Ẹyin ilé Ísírẹ́lì, èmi kò ha lè ṣe fún un yín gẹ́gẹ́ bí amọ̀kòkò yìí ti ṣe?” ni Olúwa wí. “Gẹ́gẹ́ bí amọ̀ ní ọwọ́ amọ̀kòkò bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin rí ní ọwọ́ mi, ẹ̀yin ilé Ísírẹ́lì.

7. Bí ó bá jẹ́ ìgbà kan, tí èmi kéde kí orílẹ̀ èdè tàbí ìjọba kan di fífà tu láti dojúdé àti láti parun.

8. Tí orílẹ̀ èdè ti mo kìlọ̀ fún bá yípadà kúrò nínú ìwà búburú wọn, nígbà náà ni Èmi yóò yí ọkàn mi padà níbi àjálù tí mo ti rò láti ṣe sí wọn.

9. Ní ìgbà mìíràn tí èmi bá tún kéde láti tẹ̀dó tàbí gbin orílẹ̀ èdè kan tàbí ìjọba kan.

10. Tí ó sì ṣe búburú ní ojú mi, tí kò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, nígbà náà ni èmi yóò tún ṣe rere tí mo ti fẹ́ ṣe fún wọn.

11. “Ǹjẹ́ nísìnsìnyìí, sọ fún àwọn ènìyàn Júdà àti àwọn olúgbé Jérúsálẹ́mù wí pé, ‘Báyìí ní Olúwa wí: Wò ó! Èmi ń gbérò ibi sí yin, èmi sì ń ṣe ìpinnu kan lórí yín. Nítorí náà ẹ yípadà kúrò lọ́nà búburú yín kí olúkúlúkù yín sì tún ọ̀nà àti ìṣe rè ṣe.’

12. Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ wí pé, ‘Kò se nǹkànkan, àwa yóò tẹ̀ṣíwájú nínú èrò wa, ẹnìkọ̀ọkan wa, yóò tẹ̀lé agídí ọkàn búburú rẹ̀.’ ”

13. Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí:“Ẹ bèèrè nínú orílẹ̀ èdè, ẹni tíó bá ti gbọ́ irú nǹkan wọ̀nyí ri?Ohun tí ó burú gidi ni wúndíá Ísírẹ́lì ti ṣe.

Ka pipe ipin Jeremáyà 18