Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 17:20-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Sọ fún wọ́n pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin Ọba Júdà àti gbogbo ẹ̀yin ènìyàn Júdà àti gbogbo ẹ̀yin tí ń gbé ní Jérúsálẹ́mù tí ń wọlé láti ẹnu-bodè yìí.

21. Báyìí ni Olúwa wí ẹ kíyèsi láti máa ru ẹrù lọ́jọ́ ìsinmi tàbí kí ẹ gbé wọlé láti ẹnu-bodè Jérúsálẹ́mù.

22. Má ṣe gbé ẹrù jáde kúrò nínú ilé yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe ṣe isẹ́kísẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ṣùgbọ́n kí ẹ pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ fún àwọn baba ńlá yín.

23. Ṣíbẹ̀ wọn kò gbọ́ tàbí tẹ́tí sílẹ̀, wọ́n jẹ́ Ọlọ́rùn líle; wọn kì í fẹ́ gbọ́ tàbí gba ìbáwí.

24. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá kíyèsí láti gbọ́ tèmi ní Olúwa wí, tí ẹ kò sì gbe ẹrù gba ti ẹnu bodè ìlú ní ọjọ́ ìsinmi, ṣùgbọ́n tí ẹ ya ọjọ́ ìsinmi, sí mímọ́, nípa pé ẹ kò ṣe iṣẹ́kísẹ́ ní ọjọ́ náà.

25. Nígbà náà ni Ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì yóò gba ti ẹnu-bodè wọlé pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀. Àwọn àti ìjòyè wọn yóò gun ẹsin àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wá, àwọn ọkùnrin Júdà àti àwọn olùgbé Jérúsálẹ́mù yóò tẹ̀lé wọn; ìlú yìí yóò sì di ibi gbígbé títí láéláé.

26. Àwọn ènìyàn yóò wá láti ìlú Júdà àti ní agbègbè Jérúsálẹ́mù, láti ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì àti níbi òkè gúṣù láti orílẹ̀ èdè gíga. Wọn yóò wá pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun àti orẹ ọkà ẹran, ọrẹ ọpẹ́ tùràrí àti ìyìn wá sí ilé Olúwa.

27. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá pa òfin mi mọ́ láti ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́, kí ẹ má sì ṣe ru ẹrùkẹ́rù bí ẹ̀yin yóò ṣe máa gba ti ẹnu-bodè Jérúsálẹ́mù wọlé ní ọjọ́ ìsinmi, nígbà náà ni èmi yóò da iná tí kò ní ṣe é parun ní ẹnu bodè Jérúsálẹ́mù tí yóò sì jó odi agbára rẹ̀.’ ”

Ka pipe ipin Jeremáyà 17