Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 15:9-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ìyá ọlọ́mọ méje yóò dákú, yóòsì mí ìmí ìgbẹ̀yìn. Òòrùn rẹyóò wọ̀ lọ́sàn-án gangan, yóòdi ẹni ẹ̀tẹ́ òun àbùkù. Èmiyóò fi àwọn tí ó bá yè wá síwájúàwọn ọ̀tá wọn tí idà wà lọ́wọ́ wọn,”ni Olúwa wí.

10. Áà Ó ṣe tí ìyá mi bí mi:ọkùnrin tí gbogbo ìtẹ́ tiraka tí wọ́nsì bá jà, èmi kò wín ni, bẹ́ẹ̀ nièmi ò yá lọ́wọ́ ẹni síbẹ̀, gbogbo ènìyàn ló ń fi mí ré.

11. Olúwa sọ pé,“Dájúdájú èmi ò dá ọ sí fún ìdí kan pàtó.Dájúdájú mo mú kí àwọn ọ̀tá rẹtẹríba níwájú rẹ nígbà ibi àti ipọ́njú.

12. “Ǹjẹ́ ẹnìkan lè fi ọwọ́ ṣẹ́ irinirin láti àríwá tàbí idẹ?

13. Gbogbo ọlá àti ìṣúra rẹ ni èmió fi sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkógun láìgbankànkan nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹjákèjádò orílẹ̀ èdè rẹ.

14. Èmi yóò fi ọ́ ṣẹrú fún àwọn ọ̀tá rẹní ìlú tí ìwọ kò mọ̀ nítorí ìbínúmi yóò rán iná tí yóò jó ọ.”

15. Ó yé ọ, ìwọ Olúwa rántí mi kí osì ṣe ìtọ́jú mi; gbẹ̀san mi láraàwọn tó dìtẹ̀ mi. Ìwọ ti jìyà fúnìgbà pípẹ́, má ṣe mú mi lọ, nínú bímo ṣe jìyà nítorí tìrẹ.

16. Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ dé, mo jẹ wọ́nÀwọn ni ìdùnnú àti ayọ̀ ọkàn miNítorí pé orúkọ rẹ ni a fi ń pè míÌwọ Olúwa Ọlọ́run alágbára.

17. Èmi kò fìgbà kan jókòó láàrin àwọn ẹlẹ́gàn.Má ṣe bá wọn yọ ayọ̀ pọ̀;mo dá jókòó torí pé ọwọ́ rẹ wàlára mi, ìwọ sì ti fi ìbínú rẹ kún inú mi.

Ka pipe ipin Jeremáyà 15