Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 15:15-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ó yé ọ, ìwọ Olúwa rántí mi kí osì ṣe ìtọ́jú mi; gbẹ̀san mi láraàwọn tó dìtẹ̀ mi. Ìwọ ti jìyà fúnìgbà pípẹ́, má ṣe mú mi lọ, nínú bímo ṣe jìyà nítorí tìrẹ.

16. Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ dé, mo jẹ wọ́nÀwọn ni ìdùnnú àti ayọ̀ ọkàn miNítorí pé orúkọ rẹ ni a fi ń pè míÌwọ Olúwa Ọlọ́run alágbára.

17. Èmi kò fìgbà kan jókòó láàrin àwọn ẹlẹ́gàn.Má ṣe bá wọn yọ ayọ̀ pọ̀;mo dá jókòó torí pé ọwọ́ rẹ wàlára mi, ìwọ sì ti fi ìbínú rẹ kún inú mi.

18. È é ṣe tí ìrora mi kò lópin, tí ọgbẹ́mi ń nira tí kò sì ṣe é wòsàn?Ṣe ìwọ yóò dàbí kànga ẹ̀tàn sí mi,gẹ́gẹ́ bí ìsun tó kọ̀ tí kò sun?

19. Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí:“Tí o bá ronúpìwàdà, Èmi ó dá ọ padàwá kí o lè máa sìn mí. Tí ó básọ ọ̀rọ̀ tó dára ìwọ yóò di ọ̀gbẹnusọmi. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí kọjú sí ọ;ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ kọjú sí wọn

20. Èmi fi ọ́ ṣe odi idẹ tí ó lágbárasí àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Wọn ó bá ọ jàṣùgbọ́n, wọn kò ní lè borí rẹnítorí pé, mo wà pẹ̀lú rẹ láti gbà ọ́ là,kí n sì dáàbò bò ọ́,”ni Olúwa wí.

21. “Èmi yóò gbà ọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọnìkà ènìyàn, Èmi yóò sì rà ọ́padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú.”

Ka pipe ipin Jeremáyà 15