Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 10:8-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Gbogbo wọn jẹ́ aláìlóye àti òpè, wọ́nń kọ́ ẹ̀kọ́ àwọn ère igi tí kò ní láárí

9. Sílífà tí a ti kàn ni a mú wá látiTásísì, àti wúrà láti Lépásì; èyí tíàwọn onísọ́nà àti alágbẹ̀dẹ ṣe tí wọ́nkùn ní àwọ̀ aró àti eléṣé àlùkò,èyí jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n oníṣẹ́.

10. Ṣùgbọ́n Olúwa ni Ọlọ́run tòótọ́,òun ni Ọlọ́run alààyè, Ọba ayérayé.Nígbà tí ó bá bínú, ayé yóò wárìrì;orílẹ̀ èdè kò lè fi ara da ìbínú rẹ̀.

11. “Sọ èyí fún wọn: ‘Àwọn ọlọ́run kékèèké tí kò dá ọ̀run àti ayé ni yóò ṣègbé láti ayé àti ní abẹ́ ọ̀run.’ ”

12. Ọlọ́run dá ayé pẹ̀lú agbára rẹ̀,ó dá àgbáyé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀,ó mú kí ọ̀run kí ó fẹ̀ tóbi síta nípa òye rẹ̀.

13. Nígbà tí ó bá sán àrá, àwọn omilọ́run a sì pariwo, ó mú kí ìkuùkù rusókè láti òpin ayé: ó rán mọ̀nàmọ́ná pẹ̀lú òjò,ó sì ń mú afẹ́fẹ́ wá láti ilé ìṣúra rẹ̀.

14. Gbogbo ènìyàn jẹ́ aláìlóye àti aláìnímọ̀,ojú sì ti gbogbo alágbára pẹ̀lú ère rẹ̀,èrú ni ère rẹ̀, kò sì sí ẹ̀mí nínú wọn.

15. Asán ni wọ́n, iṣẹ́ yẹ̀yẹ́ sì ni;nígbà tí ìdájọ́ wọn bá dé, wọn yóò ṣègbé.

Ka pipe ipin Jeremáyà 10