Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 10:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ fún yín ẹ̀yin ilé Ísírẹ́lì.

2. Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“Má se tọ ọ̀nà àwọn orílẹ̀ èdètàbí kí ẹ jẹ́ kí àmù òfuurufú dààmúyín, nítorí pé wọ́n ń dààmú orílẹ̀ èdè.

3. Nítorí pé asán ni asà àwọn ènìyàn,wọ́n gé igi láti inú igbó, oníṣẹ́-ọnàsì gbẹ́ ẹ pẹ̀lú àáké rẹ̀.

4. Wọ́n fi fàdákà àti wúrà ṣe élọ́sọ̀ọ́. Wọ́n fi òòlù kàn án àtièṣo kí ó má ba à ṣubú.

5. Wọ́n nàró bí igi ọ̀pẹ, òrìṣà wọnkò le è ṣọ̀rọ̀. Wọ́n gbọdọ̀ máa gbéwọn nítorí pé wọn kò lè rìn. Má ṣebẹ̀rù wọn; wọn kò le è ṣe ibi kankanbẹ́ẹ̀ ni wọn kò si lè ṣe rere kan.”

6. Kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ Olúwa;o tóbi orúkọ rẹ sì tóbi lágbára.

7. Ta ni kò yẹ kí ó bẹ̀rù rẹ Ọba àwọnorílẹ̀ èdè? Nítorí tìrẹ ni, láàrin àwọnọlọ́gbọ́n ènìyàn ní orílẹ̀ èdè àtigbogbo ìjọba wọn, kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ.

8. Gbogbo wọn jẹ́ aláìlóye àti òpè, wọ́nń kọ́ ẹ̀kọ́ àwọn ère igi tí kò ní láárí

Ka pipe ipin Jeremáyà 10