Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 46:26-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Gbogbo àwọn tí ó lọ pẹ̀lú Jákọ́bù sí Éjíbítì, àwọn tí ó jẹ́ ìran rẹ̀ tààrà láì ka àwọn aya ọmọ rẹ̀, jẹ́ ènìyàn mẹ́rìndín-ní-àadọ́rin (66).

27. Pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin méjì tí a bí fún Jósẹ́fù ní Éjíbítì àwọn ará ilé Jákọ́bù tí ó lọ sí Éjíbítì jẹ́ àádọ́rin (70) lápapọ̀

28. Jákọ́bù sì rán Júdà ṣáájú rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Jósẹ́fù, kí wọn báà le mọ ọ̀nà Gósénì. Nígbà tí wọ́n dé agbégbé Gósénì,

29. Jósẹ́fù tọ́jú kẹ̀kẹ́-ẹsin rẹ̀ ó sì lọ sí Gósénì láti pàdé Ísírẹ́lì baba rẹ̀. Bí Jósẹ́fù ti dé iwájú baba rẹ̀, ó dì mọ́ baba rẹ̀ ó sì sunkún fún ìgbà pípẹ́.

30. Ísírẹ́lì wí fún Jósẹ́fù pé, “Wàyí o, mo le kú, níwọ̀n bí mo ti rí i fún ara a mi pé, o wà láàyè ṣíbẹ̀.”

31. Nígbà náà ni Jósẹ́fù wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ àti fún àwọn ará ilé baba rẹ̀ pé, “Èmi yóò gòkè lọ, èmi yóò sì bá Fáráò sọ̀rọ̀, èmi yóò sì wí fún-un pé, Àwọn arákùnrin mi àti ìdílé baba mi tí ń gbé ní Kénánì ti tọ̀ mí wá.

32. Darandaran ni àwọn ènìyàn náà, wọ́n ń tọ́jú ẹran-ọ̀sìn, wọ́n sì kó agbo ẹran wọn àti agbo màlúù wọn àti gbogbo ohun tí wọ́n ní pẹ̀lú wá.”

33. Nígbà tí Fáráò bá pè yín wọlé tí ó sí béèrè irú iṣẹ́ tí ẹ ń ṣe,

34. ẹ fún-un lésì pé, “àwọn ìránṣẹ́ rẹ ń tọ́jú ẹran-ọ̀sìn ni láti ìgbà ewe wa wá gẹ́gẹ́ bí a ṣe ba a lọ́wọ́ àwọn baba wa.” Nígbà náà ni wọn yóò fún un yín láàyè láti tẹ̀dó sí ilẹ̀ Gósénì. Nítorí pé àwọn ará Éjíbítì kóríra ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ darandaran.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 46