Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 9:4-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ó sì sọ fún un pé, “La àárin ìlú Jérúsálẹ́mù já, kí o sì fi àmì síwájú orí gbogbo àwọn tó ń kẹ́dùn, tó sì ń sunkún nítorí ohun ìríra tí wọn ń ṣe láàrin rẹ̀.”

5. Bí mo ṣe ń fetí sí èyí, O tún sọ fún àwọn yòókù pé, “Tẹ̀lé ọkùnrin náà lọ sáàrin ìlú láti pa láì dásí àti láì ṣàánú rárá.

6. Ẹ pa arúgbó àti ọ̀dọ́mọkùnrin, ẹ pa ọlọ́mọge, obìnrin àti ọmọ kékèké, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe fọwọ́ kan àwọn tó ní àmì. Ẹ bẹ̀rẹ̀ láti ibi mímọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn àgbààgbà tó wà níwájú tẹ́ḿpìlì.

7. Nígbà náà lo sọ fún wọn pé, “Ẹ sọ tẹ́ḿpìlì náà di àìmọ́, kí òkú sì kún àgbàlá náà. Ẹ lọ!” Wọ́n jáde síta, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í pa ènìyàn láàrin ìlú.

8. Èmi nìkan ló ṣẹ́kù nígbà tí wọ́n lọ pa àwọn ènìyàn mo dójú bolẹ̀, mo kígbe pé, “Áà! Olúwa Ọlọ́run! Ìwọ yóò ha pa ìyókù Ísírẹ́lì pẹ̀lú dída ìbínú gbígbónà rẹ sórí Jérúsálẹ́mù?”

9. Ó dá mi lóhùn pé, “Ẹ̀ṣẹ̀ ilé Ísírẹ́lì àti Júdà pọ gan an ni; ilé wọn kún fún ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti àìsòótọ́. Wọ́n ní, ‘Olúwa tí kọ ilẹ̀ náà sílẹ̀; Olúwa kò sì rí wa.’

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 9