Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 8:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọjọ́ karùn-ún (5), oṣù kẹfà (6) ọdún kẹfà (6) bí mo ṣe jókòó nílé mi pẹ̀lú àwọn àgbààgbà Júdà níwájú mi, ọwọ́ Olúwa Ọlọ́run bà lé mi níbẹ̀.

2. Nígbà tí mo wò, mo rí ohun kan tí o jọ ènìyàn. Láti ibi ìbàdí rẹ lọ sísàlẹ̀ dàbí iná, láti ibi ìbàdí yìí sókè sì mọ́lẹ̀ bí idẹ tó ń kọ mọ̀nà.

3. Ó na ohun tó dàbí ọwọ́ jáde, ó fi gba mi nírun orí mú, Ẹ̀mí sì gbé mi sókè sí agbede-méjì ayé àti ọ̀run, ó sì mú mi lọ rí ìran Ọlọ́run, mo sì lọ sí Jérúsálẹ́mù, sí ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà òde àríwá níbi tí ère tí ó ń mú ni bínú wá níwájú mi,

4. Sì kíyèsíi, ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì wà níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìran ti mo rí ni pẹ̀tẹ́lẹ̀

5. Ó sì sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, gbójú sókè sí ìhà àríwá.” Èmi náà sì gbójú sókè sí ìhà àríwá mo sì rí ère tí ó ń mú ni jowú ní ẹnu ọ̀nà ibi pẹpẹ.

6. Ó sì wí fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, ṣé o rí ohun tí wọ́n ń ṣe-ohun ìríra ńlá tí ilé Ísírẹ́lì ń ṣe, láti lé mi jìnnà réré sí ibi mímọ́ mi? Ṣùgbọ́n ìwọ ó tún rí àwọn ìríra ńlá tó tóbi jù yí lọ.”

7. Ó mú mi wá sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá. Mo wò ó, mo sì rí ihò kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri.

8. Nígbà náà ló sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, gbẹ́ inú ògiri náà,” nígbà tí mo sì gbẹ́ inú ògiri, mo rí ìlẹ̀kùn kan.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 8