Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 7:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:

2. “Ọmọ, ènìyàn báyìí ni Olúwa Ọlorún wí sí ilé Ísírélì: Òpin! Òpin ti dé sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ náà.

3. Òpin tí dé sí ọ báyìí n ó sì tú ìbínú mi jáde sí ọ, n ó dájọ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìwà rẹ, ń ó sì san-an fún ọ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìwà ìríra rẹ.

4. Ojú mi kò ní i dá ọ sì bẹ́ẹ̀ ni ń kò sì ní wò ọ́ pẹ̀lú àánú; ṣùgbọ́n ń ó san án fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ àti gbogbo ìwà ìríra tó wà láàrin rẹ. Nígbà náà ní ẹ o mọ̀ pé èmi ni Olúwa.

5. “Èyí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Àjálù, àjálù lórí àjálù ń bọ̀;

6. Òpin ti dé! Òpin ti dé, ó ti dìde lòdì sí ọ. Ó ti dé!

7. Ìparun ti dé sórí yín gbogbo, ẹ̀yin tó ń gbé ní ilẹ̀ náà. Àsìkò ti tó, ọjọ́ wàhálà ti súnmọ́ etílé; kì í ṣe ọjọ́ ariwo ayọ̀ lórí òkè.

8. Mo ṣetán láti tú ìbìnú gbígbóná mi lé ọ lórí àti láti lo ìbínú mi lórí rẹ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀nà rẹ, n ó sì san án fún ọ gẹ́gẹ́ bi gbogbo ìwà ìríra rẹ.

9. Ojú mi kò ní i dá ọ sí, ń kò sì ní wò ọ́ pẹ̀lú àánú; ń o san-an fún ọ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀nà ìwà àti gbogbo ìwà ìríra tí wà láàrin rẹ. Nígbà náà ní ẹ o mọ̀ pé èmi Olúwa lo kọlù yín.

10. “Ọjọ́ náà ti dé! O ti dé: Ìparun ti bú jáde, ọ̀pá ti tan ná, ìgbéraga ti sọ jáde!

11. Ìwà ipá ti di ọ̀pá ìwà búburú; kò sí nínú wọn tí yóò ṣẹ́kú, tàbí nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn, kò sí ọrọ̀ ko si ohun ti o niye.

12. Àsìkò náà ti tó; ọjọ́ náà tidé, kí ẹni tó n rajà má se yọ̀ bẹ́ẹ̀ ni ki ontàjà má ṣe ṣọ̀fọ̀; torí, ìbínú gbígbóná wà lórí gbogbo ènìyàn.

13. Nítorí pé ontàjà kò ni ri ilé tó tà gbà níwọ̀n ìgbà ti awọ̀n méjèèjì bá wà láyé; torí ìran tó kan ènìyàn yìí kò ní yí padà. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò gba ara rẹ̀ là.

14. Bí wọn tilẹ̀ fọn fèrè ogun tí wọ́n sì pèsè ohun gbogbo sílẹ̀, kò sẹ́ni tí yóò lọ ojú ogun, torí ìbínú gbígbóná mi ti wà lórí gbogbo ènìyàn

15. “Idà wà níta, àjàkálẹ̀-àrùn àti ìyàn wà nílé, idà yóò pa ẹní tó bá wà ní orílẹ èdè, àjàkálẹ̀-àrùn àti ìyàn yóò pa ẹni tó bá wà ní ìlú.

16. Gbogbo àwọn tí ó bọ́ nínú wọn yóò sálà, wọn yóò sì wà lórí òkè bí i àdàbà inú àfonífojì, gbogbo wọn yóò máa ṣọ̀fọ̀, olúkúlùkù nítorí àìṣedédé rẹ̀.

17. Gbogbo ọwọ́ yóò rọ, gbogbo orúnkún yóò di aláìlágbára bí omi.

18. Wọn o wọ aṣọ ọ̀fọ̀ ẹ̀rù yóò sì bò wọ́n mọ́lẹ̀, ìtìjú yóò mù wọn, wọn ó sì fá irun wọn.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 7