Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 5:2-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Nígbà tí ọjọ́ ìgbóguntì bá parí, sun ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta ìrun yìí níná láàrin ìlú. Mú ìdá kan nínú mẹ́ta kí o fi idà bù ú káàkiri ìlú. Kí o sì tú ìdá kan yóòkù ká sínú afẹ́fẹ́. Nítorí pé pẹ̀lú idà ni èmi yóò máa lé wọn ká.

3. Ṣùgbọ́n mú díẹ̀ nínú irun yìí kí o sì ta á mọ́ etí aṣọ rẹ.

4. Tún ju díẹ̀ nínú irun yìí sínú iná, kí o sun ún níná. Torí pé láti ibẹ̀ ni iná yóò ti jáde lọ sí gbogbo ilé Ísírẹ́lì.

5. “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Èyí ní Jérúsálẹ́mù, tí mo gbé kalẹ̀ sí àárin àwọn orílẹ̀ èdè, pẹ̀lú àwọn ìlú gbogbo tí o yí i ká.

6. Síbẹ̀ nínú ìwà búburú rẹ̀ ó ti ṣọ̀tẹ̀ si òfin àti ìlànà mi ju àwọn orílẹ̀ èdè àti àwọn ilẹ̀ tó yí i ká lọ. Ó ti kọ òfin mi sílẹ̀, kò sì pa ìlànà mi mọ́.

7. “Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Nítorí pé o ti ṣe àìgbọ́ràn ju àwọn orílẹ̀ èdè tó yí ọ ká lọ, tí o kò sì tẹ̀lé ìlànà mi tàbí kí o pa òfin mi mọ́. O kò tilẹ̀ tún ṣe dáadáa tó àwọn orílẹ̀ èdè tó yí ọ ká.

8. “Nítorí náà báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Èmi gan an lòdì sí ọ, Jérúsálẹ́mù, n ó sì jẹ ọ́ níyà lójú àwọn orílẹ̀ èdè tó yí ọ ká.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 5