Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 5:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Báyìí, ọmọ ènìyàn, mú ìdá tí ó mú kí o sì fi se abẹ ìfárí onígbàjámọ̀, kí o fi fá irun orí àti irùngbọ̀n rẹ. Fi irun yìí sórí ìwọ̀n kí o sì pín in.

2. Nígbà tí ọjọ́ ìgbóguntì bá parí, sun ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta ìrun yìí níná láàrin ìlú. Mú ìdá kan nínú mẹ́ta kí o fi idà bù ú káàkiri ìlú. Kí o sì tú ìdá kan yóòkù ká sínú afẹ́fẹ́. Nítorí pé pẹ̀lú idà ni èmi yóò máa lé wọn ká.

3. Ṣùgbọ́n mú díẹ̀ nínú irun yìí kí o sì ta á mọ́ etí aṣọ rẹ.

4. Tún ju díẹ̀ nínú irun yìí sínú iná, kí o sun ún níná. Torí pé láti ibẹ̀ ni iná yóò ti jáde lọ sí gbogbo ilé Ísírẹ́lì.

5. “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Èyí ní Jérúsálẹ́mù, tí mo gbé kalẹ̀ sí àárin àwọn orílẹ̀ èdè, pẹ̀lú àwọn ìlú gbogbo tí o yí i ká.

6. Síbẹ̀ nínú ìwà búburú rẹ̀ ó ti ṣọ̀tẹ̀ si òfin àti ìlànà mi ju àwọn orílẹ̀ èdè àti àwọn ilẹ̀ tó yí i ká lọ. Ó ti kọ òfin mi sílẹ̀, kò sì pa ìlànà mi mọ́.

7. “Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Nítorí pé o ti ṣe àìgbọ́ràn ju àwọn orílẹ̀ èdè tó yí ọ ká lọ, tí o kò sì tẹ̀lé ìlànà mi tàbí kí o pa òfin mi mọ́. O kò tilẹ̀ tún ṣe dáadáa tó àwọn orílẹ̀ èdè tó yí ọ ká.

8. “Nítorí náà báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Èmi gan an lòdì sí ọ, Jérúsálẹ́mù, n ó sì jẹ ọ́ níyà lójú àwọn orílẹ̀ èdè tó yí ọ ká.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 5