Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 44:25-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. “ ‘Àlùfáà kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nípa sísún mọ́ òkú ènìyàn; ṣùgbọ́n ti òkú ènìyàn yẹn bá jẹ́ bàbá tàbí ìyá rẹ̀, àbúrò rẹ̀ ọkùnrin tàbí àbúrò rẹ̀ obìnrin ti kò i ti lọ́kọ, nígbà náà o le sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́.

26. Lẹ́yìn ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, ki òun kí ó dúró fún ọjọ́ méje.

27. Ní ọjọ́ ti yóò wọ àgbàlá ti inú ni ibi mímọ́ láti se ìránṣẹ́ ibi mímọ́, ni kí òun kí o rú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni Olúwa Ọba wí.

28. “ ‘Èmi ni kì ó jẹ́ ogún tí àwọn Àlùfáà yóò ní. Ẹ kò gbọdọ̀ fún wọn ni ìpín kankan ní Ísírẹ́lì; Èmi ni yóò jẹ́ ìpín wọn.

29. Wọn yóò jẹ ọrẹ ẹbọ jíjẹ, ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ ìrékọjá; gbogbo ohun tí a bá yà sọ́tọ̀ fún Olúwa ni Ísírẹ́lì ni yóò jẹ́ ti wọn.

30. Èyí tí ó dára jùlọ nínú gbogbo àkọ́so èso àti ti ẹ̀bùn pàtàkì yóò jẹ́ ti àwọn àlùfáà. Ẹ ní láti fún wọn ní ìpín àkọ́kọ́ nínú èso ilẹ̀ yìí kí ìbùkún lè wà lórí gbogbo ilé yìí.

31. Àwọn àlùfáà kò gbọdọ̀ jẹ́ ohunkóhun bí i ẹyẹ tàbí ẹrankọ, tí ó ti kú fúnra rẹ̀ tàbí èyí ti ẹranko ńlá fà ya.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 44