Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 44:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn náà ni ọkùnrin náà mú mi padà lọ sí ibi mímọ́, èyí tí ó kọjú sí ìhà ìlà oòrùn, ó sì wà ní títì.

2. Olúwa sọ fún mi, “Ẹnu ọ̀nà yìí ni kí ó wà ní títì. A kò gbọdọ̀ sí i sílẹ̀; kò sí ẹni tí o gbọdọ̀ gba ibẹ̀ wọlé. Ó gbọdọ̀ wà ní títì nítorí pé Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì tí gbà ibẹ̀ wọlé.

3. Ọmọ aládé fúnra rẹ̀ ní o lè jókòó ní ẹnu ọ̀nà náà kí o sì jẹun níwájú Olúwa. Ó gbọdọ̀ gba ọ̀nà ìlóro ẹnu ọ̀nà wọlé kí ó sì gba ibẹ̀ jáde.”

4. Lẹ́yìn náà, ọkùnrin náà mú mi gba ẹnu ọ̀nà àríwá lọ sí iwájú ilé Ọlọ́run. Mo wò ó mo sì rí ògo Olúwa tí ó kún inú ilé Olúwa, mo sì dojúkọ ilẹ.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 44