Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 41:16-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. àti pẹ̀lú àwọn ìloro ilé àti àwọn fèrèsé tóóró pẹ̀lú ọ̀dẹ̀dẹ̀ lókè yípo àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, gbogbo rẹ̀ ní ìta papọ̀ mọ́ ìloro ilé ni wọ́n fi igi bò. Ilẹ̀ ògiri sókè títí dé ojú fèrèsé ni wọ́n fi igi bò pátapáta.

17. Ní ìta gbangba lókè ìta ẹnu ọ̀nà inú ibi mímọ́ àti lára ògiri pẹ̀lú àlàfo tí kò ju ara wọn lọ yípo inú ìta ibi mímọ́

18. ní wọn fín àwọn kérúbù àti àwọn igi ọ̀pẹ. Wọn fi àwọn igi ọ̀pẹ bo àárin àwọn kérúbù. Kérúbù kọ̀ọ̀kan ní ojú méjìméjì:

19. Ojú ènìyàn sí ìhà igi ọ̀pẹ ni ẹ̀gbẹ́ kan, ojú ọ̀dọ́ kìnnìún sí ìhà igi ọ̀pẹ ní ẹ̀gbẹ́ kejì. Wọn fín gbogbo rẹ̀ yípo gbogbo ilé Ọlọ́run.

20. Láti ilẹ̀ sí agbègbè òkè ẹnu ọ̀nà, àwọn Kérúbù àti àwọn igi ọ̀pẹ ni wọ́n fín si ara ògiri ìta ibi mímọ́.

21. Ìta ibi mímọ́ ni férémù onígun mẹ́rin pẹ̀lú ìkan tí ó wà ní ibi mímọ́ jùlọ rí bákan náà.

22. Pẹpẹ ìrúbọ kan tí a fi igi ṣe wà, gíga rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì, àwọn igun rẹ̀, ìsàlẹ̀ rẹ̀ àti ògiri rẹ́ jẹ́ igi. Ọkùnrin náà sọ fún mi pé, “Èyí yìí ní tẹ́ḿpìlì tí ó wà ní iwájú Olúwa.”

23. Ìta ibi mímọ́ àti ibi mímọ́ jùlọ ni ilẹ̀kùn méjì papọ̀.

24. Lẹ̀kùn kọ̀ọ̀kan ní ewé méjìméjì, ewé méjì tí a gbe kọ́ fún ẹnu ọ̀nà kọ̀ọ̀kan.

25. Ní ẹnu ilẹ̀kùn ní ìta ibi mímọ́ ni àwọn kérúbù àti igi ọ̀pẹ tí a fín bí ti àwọn tí a fín si àwọn ara ògiri, ìbòrí tí á fí igi ṣe wà ní iwájú ẹnu ọ̀nà ilé ní ìta.

26. Ní ẹ̀gbẹ́ àwọn ògiri ẹnu ọ̀nà ní àwọn fèrèsé tóóró pẹ̀lú igi ọ̀pẹ tí a fín ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì wà. Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ilé Ọlọ́run náà ni ìbòrí tí a fi igi ṣe.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 41