Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 38:10-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. “ ‘Èyí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Ní ọjọ́ náà èrò kan yóò wá ṣọ́kan rẹ, ìwọ yóò sì pète ìlànà búbúru.

11. Ìwọ yóò wí pé, “Èmi yóò gbé Ogun ti ilẹ̀ àwọn tí a kò fi odi yíká: Èmi yóò gbé ogun ti àwọn ènìyàn àlàáfíà tí a kò furasí-gbogbo wọn ń gbé ní àìsí odi, ní àìsí ẹnu ọ̀nà òde àti àsígbà.

12. Èmi yóò mú ohun ọdẹ, èmi yóò sì kó ìkógun, èmi yóò sì yí ọwọ́ mi padà sí ibi ìwólulẹ̀ ti a ti tún kọ́, àwọn ènìyàn tí a kójọpọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè, tí ó ní ọrọ̀ nínú nǹkan ọ̀sìn àti ẹrú, tí ó ń gbé ní àárin gbùngbùn ilẹ̀ náà.”

13. Ṣébà, Dédánì àti àwọn oníṣòwò Táṣíṣì àti gbogbo ìletò rẹ yóò sọ fún un yín pé, “Ṣé ẹ̀yin wá fún ìkógun? Ṣé ẹ̀yin ti kó àwọn ìjọ yín jọpọ̀ fún ìkógun, láti kó silífà àti wúrà lọ, láti kó nǹkan ọ̀sìn àti ẹrú àti láti gba ọ̀pọ̀ ìkógun?” ’

14. “Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, ṣọtẹ́lẹ̀ kí ó sì ṣọ fún Gógì: ‘Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Ní ọjọ́ náà, nígbà tí àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì ń gbé ní àìléwu, ìwọ kì yóò ha ṣe àkíyèsí rẹ̀?

15. Ìwọ yóò wá láti ààyè rẹ ní jìnnàjìnnà àríwá, ìwọ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè pẹ̀lú rẹ, gbogbo wọn yóò sì gun ẹsìn ìjọ ńlá, jagunjagun alágbára.

16. Ìwọ yóò tẹ̀síwájú ní ìlòdì sí àwọn Ísírẹ́lì ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bí ìkùùkuu tí ó bo ilẹ̀. Ni àwọn ọjọ́ tí ń bọ̀, ìwọ Gógì, èmi yóò mú ọ wá ní ìlòdì sí ilẹ̀ mi, kí àwọn orílẹ̀ èdè lè mọ̀ mi nígbà tí mo bá fí ara hàn ni mímọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ ní ojú wọn.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 38