Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 36:4-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. nítorí náà, Ẹ̀yin òkè gíga Ísírẹ́lì gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun: Èyí yìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí fún àwọn òkè gíga àti àwọn òkè kékèké, fún àfonífojì ńlá àti àfonífojì kékèké, fún àwọn ibi ìsọdahoro ìparun àti fún àwọn ìlú tí a ti kọ̀ sílẹ̀ tí a ti kó tí àwọn orílẹ̀ èdè tí ó kù ní àyíká sì fi ṣe ẹlẹ́yà

5. Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Ní ìgbóná ọkàn ní mo sọ̀rọ̀ lòdì sí Édómù, nítorí pẹ̀lú ayọ̀ àti ìyodì ní ọkàn wọn ní wọ́n sọ ilé mi di ohun ìní wọn, kí wọn kí o lè kó pápá oko tútù rẹ̀.’

6. Nítorí náà, sọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Ísírẹ́lì náà kí o sì sọ sí àwọn òkè gíga náà àti àwọn òkè kékèké, sí àwọn àfonífojì ńlá àti sí àwọn àfonífojì kéékèèkéé: ‘Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi sọ̀rọ̀ nínú ìrunú owú mi nítorí pé ìwọ ti jìyà ìfiṣẹ̀sín àwọn orílẹ̀ èdè.

7. Nítorí náà, Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi ṣe ìbúra nípa nína ọwọ́ mi sókè pé; àwọn orílẹ̀ èdè àyíká rẹ náà yóò jìyà ìfiṣẹ̀sín.

8. “ ‘Ṣùgbọ́n ìwọ, òkè gíga Ísírẹ́lì, yóò mú ẹ̀ka àti èso fún àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì, nítorí wọn yóò wá sílé ní àìpẹ́ yìí.

9. Èmi ń ṣe àníyàn fún ọ, èmi yóò sì fi rere wọ̀ ọ́; àwa yóò tu ọ́, àwa yóò sì gbìn ọ́,

10. èmi yóò sì sọ iye àwọn ènìyàn di púpọ̀ nínú rẹ àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì. Àwọn ìlú yóò di ibùgbé, a óò sì tún àwọn ibi ìparun kọ́.

11. Èmi yóò sọ iye ènìyàn àti ẹran dì púpọ̀ nínú yín, wọn yóò sì so èso, wọn yóò sì di púpọ yanturu. Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn máa gbé nínú rẹ bí ti àtẹ̀yìnwá, èmi yóò sì mú kí o ṣe rere ju ìgbà àtijọ́ lọ. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ pé èmi ni Olúwa.

12. Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn, àní àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì, rìn lórí rẹ̀. Wọn yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì di ogún ìní wọn; ìwọ kì yóò sì gba àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ wọn mọ́.

13. “ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Nítorí pé àwọn ènìyàn sọ fún ọ pé, “Ìwọ pa àwọn ènìyàn run, ìwọ sì gba àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè lọ́wọ́ wọn,”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 36