Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 35:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:

2. “Ọmọ ènìyàn kọjú sí òkè Séírì; ṣọtẹ́lẹ̀ síi

3. Kí o sì sọ wí pé: ‘Èyí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmí lòdì sí ọ, òkè Séírì, Èmi yóò sì na ọwọ́ mi síta ní ìlòdì sí ọ, èmi yóò sì mú kí o di ahoro.

4. Èmì yóò pa àwọn ìlú rẹ run, ìwọ yóò sì di ahoro. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.

5. “ ‘Nítorí ìwọ dá ààbò bo ọ̀tẹ̀ àtayébáyé, tí ìwọ sì fi Ísírẹ́lì lé idà lọ́wọ́, ní àsìkò ìdààmú wọn, ní àsìkò tí ìjìyà wọn dé góńgó,

6. nítorí náà bi mo ti wà láàyè, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, èmi yóò fi ọ kalẹ̀ fún ìtàjẹ̀ sílẹ̀, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ yóò sì lépa rẹ. Níwọ̀n ìgbà tí ìwọ kò ti korìíra ìtàjẹ̀-sílẹ̀, ìtàjẹ̀-sílẹ̀ yóò sì lépa rẹ.

7. Èmi yóò mú kí òkè Séírì di ahoro; ọ̀fọ̀ gbogbo àwọn tí ó ńlọ tí ó ń bọ̀ ní èmi yóò gé kúrò lára rẹ.

8. Èmi yóò fi àwọn tí a pa kún orí òkè rẹ: àwọn tí a fi idà pa yóò ṣubú ní orí òkè rẹ, àti ní àárin àwọn òkè rẹ.

9. Èmi yóò mú kí o di ahoro títí láé; Kò ní sí olùgbé ní ìlú rẹ. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.

10. “ ‘Nítorí tí ìwọ sọ pé, “Àwọn orílẹ̀ èdè àti ilẹ̀ méjì wọ̀nyí yóò jẹ́ tiwa, àwa yóò sì gbà wọ́n ní ìní,” bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi Olúwa wà níbẹ̀,

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 35