Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 3:17-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. “Ọmọ ènìyàn, mo ti fi ọ́ ṣe òlùṣọ́ fún ìle Ísírẹ́lì; nítorí náà gbọ́ ọ̀rọ̀ tí mo ń sọ, fún wọn ní ìkìlọ̀ láti ọ̀dọ̀ mi.

18. Bí mo bá sọ fún ènìyàn búburú pé dájúdájú, ‘Ìwọ yóò kú’, tí ìwọ kò sì kìlọ̀ fún ènìyàn búburú yìí láti dáwọ́ ìwà ibi rẹ̀ dúró, kí o sì gba ẹ̀mí rẹ̀ là, ènìyàn búburú náà yóò kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ní ọwọ́ rẹ ni èmi yóò ti béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.

19. Ṣùgbọ́n bí o bá kìlọ̀ fún ènìyàn búburú, tí ó kọ̀ tí kò fi ìwà búburú rẹ̀ sílẹ̀, yóò kú sínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; ṣùgbọ́n ọrùn tìrẹ ti mọ́.

20. “Bákan náà, bí olódodo kan bá yípadà, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àìsòdodo, tí mo sì fi ohun ìkọ̀sẹ̀ sí ọ̀nà rẹ̀, yóò kú sínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Nítorí pé ìwọ kọ̀ láti kìlọ̀ fún un, yóò kú sínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, a ó gbàgbé gbogbo ìwà rere tó ti hù tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ní ọwọ́ rẹ̀ ni èmi yóò ti béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.

21. Ṣùgbọ́n bí o bá kìlọ̀ fún olódodo tó sì dáwọ́ ìwà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ dúró, dájúdájú òun yóò yè nítorí pé ó ti gba ìkìlọ̀, ọrùn tìrẹ sì mọ́.”

22. Ọwọ́ Olúwa wà lára mi níbẹ̀, ó sì wí fún mi pé, “Dìde, lọ sí ibi tí ó tẹ́jú, èmi yóò sì bá ọ sọ̀rọ̀ níbẹ̀.”

23. Mo sì dìde mo lọ sí ibi tí ó tẹ́jú. Ògo Olúwa dúró níbẹ̀, ó dàbí irú ògo tí mo rí létí odò Kébárì, mo sì dojúbolẹ̀.

24. Nígbà náà ni Ẹ̀mí wọ inú mi, tí ó sì tún gbé mi dúró. Ó sì wí fún mi pé: “Lọ, ti ara rẹ mọ́ inu ilé rẹ

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 3