Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 29:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọjọ́ kejìlá, oṣù kẹ́wàá, ọdún kẹ́wàá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:

2. “Ọmọ ènìyàn, kọjú sí Fáráò ọba Éjíbítì kí ó sì sọ àṣọ̀tẹ́lẹ̀ sí i àti sí gbogbo Éjíbítì.

3. Sọ̀rọ̀, kí ó sì wí pé: ‘Báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Èmi lòdì sí ọ, Fáráò ọba Éjíbítììwọ dírágónì ńlá inú òkun tí ó dùbúlẹ̀ síàárin àwọn odò ṣíṣàn rẹèyí tí ó sọ wí pé, “Tèmi ni odò Náílì;èmi ni ó sì ṣe é fún ara mi.”

4. Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ìwọ̀ mú ẹnu rẹèmi yóò sì mú ẹja inú odò rẹgbogbo lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ.Èmi yóò fà ọ́ síta kúrò láàrin àwọn odò rẹ,àti gbogbo ẹja odò rẹ yóò lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ.

5. Èmi yóò sọ ọ́ nù sí ihàìwọ àti gbogbo ẹja inú odò rẹ:ìwọ yóò ṣubú sí gbangba okoa kì yóò sì ṣà ọ́ jọ tàbí gbé ọ sókè.Èmi ti fi ọ ṣe oùnjẹ fún àwọn ẹranko igbóàti fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run láti jẹ.

6. Nígbà náà gbogbo àwọn olùgbé ni Ijíbítì yóò mọ pé Èmi ni Olúwa.“ ‘Ìwọ ti jẹ́ ọ̀pá ìyè fún ilé Ísírẹ́lì.

7. Nígbà tí wọn fi ọwọ́ agbára wọn dì ọ́ mú. Ìwọ fọ́, ìwọ sì ya gbogbo èjìká wọn; nígbà tí wọn fi ara tì ọ́, ìwọ sẹ́, ìwọ sì mú gbogbo ẹ̀gbẹ́ wọn gbọ̀n.

8. “ ‘Nítorí náà, èyí yìí ní Olúwa Ọlọ́run wí: kéyèsí i Èmi yóò mú idà kan wá sórí rẹ tí yóò sì gé ènìyàn àti ẹran kúrò nínú rẹ.

9. Ilẹ̀ Éjíbítì yóò di ihà àti ahoro, nígbà náà ní wọn yóò sì mọ̀ wí pé èmi ní Olúwa.“ ‘Nítorí tí ìwọ wí pé, “Tèmi ni odò Náílì; Èmi ni mo ṣe é,”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 29