Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 27:20-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. “ ‘Dédánì ni oníṣòwò rẹ ní aṣọ ìjókòó-lẹ́sin fún ẹṣin-gígùn.

21. “ ‘Àwọn ará Árábù àti gbogbo àwọn ọmọ aládé Kédárì àwọn ni àwọn onibárà rẹ: ní ti ọ̀dọ́ àgùntàn, àgbò àti ewúrẹ́, nínú ìwọ̀nyí ni wọ́n ti jẹ́ oníbárà rẹ.

22. “ ‘Àwọn oníṣòwò ti Ṣébà àti Rámà, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọ́n ta onírúurú tùràrí olóòórùn dídùn dáradára ní ọjà rẹ, àti àwọn òkúta iyebíye àti wúrà.

23. “ ‘Áránì àti Kánnà àti Édénì, àwọn onísòwò Ṣébà, Ásúrù àti Kílímádì, ni àwọn oníṣòwò rẹ.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 27