Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 27:16-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. “ ‘Árámù ṣòwò pẹ̀lú nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ òwò rẹ̀; wọn ṣe ìpààrọ̀ òkúta iyebíye, òwú elésèé àlùkò, iṣẹ́ ọ̀nà tí a fi abẹ́rẹ́ ṣe, asọ ọ̀gbọ̀ dáradára, ìlẹ̀kẹ̀ iyùn pupa fún ọjà títà rẹ.

17. “ ‘Júdà àti Ísírẹ́lì, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọn ṣe ìpààrọ̀ ọkà, Mínnítì, àkàrà àdídùn; pannági, oyin, epo àti ìpara olóòórùn dídùn ni wọ́n fi ná ọjà rẹ.

18. “ ‘Dámásíkù, ni oníṣòwò rẹ, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ọjà tí ó ṣe àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀; ní ti ọtí wáìnì tí Helíbónì, àti irun àgùntàn funfun.

19. “ ‘Àwọn ará Dánì àti Gíríkì láti Úsálì ra ọjà títà rẹ; irin dídán, káṣíà ati kálámù ni àwọn ohun pàsípààrọ̀ ní ọjà rẹ.

20. “ ‘Dédánì ni oníṣòwò rẹ ní aṣọ ìjókòó-lẹ́sin fún ẹṣin-gígùn.

21. “ ‘Àwọn ará Árábù àti gbogbo àwọn ọmọ aládé Kédárì àwọn ni àwọn onibárà rẹ: ní ti ọ̀dọ́ àgùntàn, àgbò àti ewúrẹ́, nínú ìwọ̀nyí ni wọ́n ti jẹ́ oníbárà rẹ.

22. “ ‘Àwọn oníṣòwò ti Ṣébà àti Rámà, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọ́n ta onírúurú tùràrí olóòórùn dídùn dáradára ní ọjà rẹ, àti àwọn òkúta iyebíye àti wúrà.

23. “ ‘Áránì àti Kánnà àti Édénì, àwọn onísòwò Ṣébà, Ásúrù àti Kílímádì, ni àwọn oníṣòwò rẹ.

24. Wọ̀nyí ní onírúurú nǹkan: aṣọ aláró, àti oniṣẹ́-ọnà àti àpótí aṣọ oníyebíye, tí a fi okùn dì, tí a sì fi igi kédárì ṣe, nínú àwọn ilé-ìtajà rẹ.

25. “ ‘Àwọn ọkọ̀ Táṣíṣì ní èròní ọjà rẹa ti mú ọ gbilẹ̀a sì ti ṣe ọ́ lógoní àárin gbungbun òkun

26. Àwọn atukọ̀ rẹ ti mú ọwá sínú omi ńlá.Ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn yóò fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́ní àárin gbùngbùn òkun.

27. Ọrọ̀ rẹ, ọjà rẹ àti àwọn ohun títà rẹ,àwọn atọ́kọ̀ rẹ, òṣìṣẹ́ ìtukọ̀ rẹ.Àwọn oníbárà rẹ àti gbogbo àwọnjagunjagun rẹ, tí ó wà nínú rẹàti nínú gbogbo ẹgbẹ́ rẹtí ó wà ní àárin rẹyóò rì sínú àárin gbùngbùn òkunní ọjọ́ ìparun rẹ.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 27