Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 25:5-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Èmi yóò sì sọ Rábà di ibùjẹ, fún àwọn ìbákasíẹ àti àwọn ọmọ Ámónì di ibùsùn fún agbo ẹran. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.

6. Nítorí báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Nítorí pé ìwọ pàtẹ́wọ́, ìwọ sì jan ẹsẹ̀ mọ́lẹ̀, tí ìwọ ń yọ̀ pẹ̀lú gbogbo àrankàn rẹ sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì

7. nítorí náà, èmi yóò na ọwọ́ mi lé ọ, èmi yóò sì fi ọ fún àwọn aláìkọlà fún ìkógun. Èmi yóò sì gé ọ kúrò láàrin àwọn ènìyàn, èmi yóò sì jẹ́ kí o parun kúrò ni ilẹ̀ gbogbo. Èmi yóò sì pa ọ́ run, ìwọ yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa.

8. “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: ‘Nítorí pé Móábù àti Séírì sọ wí pé, “Wò ó, ilé Júdà ti dàbí gbogbo àwọn aláìkọlà,”

9. nítorí náà Èmi yóò sí Móábù sílẹ̀ láti àwọn ìlú gbogbo tí ó wà ní ààlà rẹ̀, ògo ilẹ̀ náà, Bétjẹ́símótì, Báálì-Méónì àti Kíríátaímù.

10. Èmi yóò fi Móábù pẹ̀lú àwọn ará Ámónì lé àwọn ènìyàn ìlà oòrùn ní ìní, kí a má bà á lè rántí àwọn ará Ámónì láàrin orílẹ̀ èdè gbogbo;

11. Èmi yóò sì mú ìdájọ́ ṣsẹ sí Móábù lára, wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’ ”

12. “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí pé: ‘Nítorí pé Édómù gbẹ̀san lára ilé Júdà, ó sì jẹ̀bi gidigidi nípa síse bẹ́ ẹ̀,

13. nítorí náà báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí pé: Èmi yóò na ọwọ́ mi sórí Édómù èmi yóò sì pa àwọn ènìyàn àti àwọn ẹranko rẹ̀. Èmi yóò fi sófo láti Temanì dé Dédánì yóò ti ipa idà ṣsubú.

14. Èmi yóò gbẹ̀san lára Édómù láti ọwọ́ àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì, wọn sì se ṣsi Édómù gẹ́gẹ́ bí ìbínú àti ìrunú mi: wọn yóò mọ̀ ìgbẹ̀san mi ní Olúwa Ọlọ́run wí.’ ”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 25