Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 24:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọdún kẹsàn án, oṣù kẹwàá, ọjọ́ kẹwàá, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:

2. “Ọmọ ènìyàn, kọ ọjọ́ náà sílẹ̀, ọjọ́ náà gan an, nítorí Ọba Bábílónì náà ti dojúti Jérúsálẹ́mù ní ọjọ́ yìí gan an.

3. Sì pa òwe yìí fún ilé ọlọ́tẹ̀ náà, sọ fún wọn pé: ‘Èyí yìí ni Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Gbé ìkòkò ìdáná náà ka iná:Gbé e kaná kí o sì da omi sí i nínú.

4. Kó àwọn ègé ẹran tí a gé náà sínú rẹ̀,gbogbo àwọn ègé ẹran tí ó tóbi, itan àti apá.Kó àwọn egungun tí ó dára jù sínú rẹ̀

5. Mú àwọn tí ó jọjú nínú agbo ẹran.Kó àwọn egungun sí abẹ́ ẹ rẹ̀;sì jẹ́ kí ó hó dára dárasì jẹ́ kí àwọn egungun náà bọ̀ nínú rẹ̀.

6. “ ‘Nítorí báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Ègbé ni fún ìlú ẹlẹ́jẹ̀ náà,fún ìkòkò náà tí èrúru wà nínú rẹ̀tí èrúru kò dà kúrò lójú rẹ̀!Mú ẹran náà jáde ní ekìrí ekìrímá ṣe ṣà wọ́n mú.

7. “ ‘Nítorí ẹ̀jẹ̀ tí ó ta sílẹ̀ wà ní àárin rẹ̀;o dà á sí orí àpáta kan lásánkò dà á sí orí ilẹ̀,níbi ti erùpẹ̀ yóò ti bò ó

8. Láti bá à le jẹ́ kí ìbínú kí ó dé láti gbẹ̀sanmo da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí orí àpáta kan lásán,kí o ma bà á wà ni bíbò.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 24