Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 23:27-44 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Èmi yóò sì fi òpin sí ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti iṣẹ́ aṣẹ́wó tí ẹ bẹ̀rẹ̀ ni Éjíbítì. Ẹ̀yin kò ní wo àwọn nǹkan wọ̀nyí pẹ̀lú aáyun, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní rántí Éjíbítì mọ.

28. “Nítorí báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò fi ọ lé ọwọ́ àwọn tí ó korìíra, lọ́wọ́ àwọn ẹni tí ọkàn rẹ ti sí kúrò.

29. Wọn yóò fìyà jẹ ọ́ pẹ̀lú ìkórìíra, wọn yóò sì kó gbogbo ohun tí o ṣiṣẹ́ fún lọ. Wọn yóò fi ọ́ sílẹ̀ ní ìhòòhò goloto, ìtìjú iṣẹ́ aṣẹ́wó rẹ ni yóò farahàn. Ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti ìdàrúdàpọ̀ rẹ

30. ni ó mú èyí wá sórí rẹ, nítorí tí ìwọ ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ si orílẹ̀ èdè, o sì fi àwọn òrìṣà rẹ́ ara rẹ jẹ.

31. Ìwọ ti rin ọ̀nà ti ẹ̀gbọ́n rẹ rìn; Èmi yóò sì fi aago rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́.

32. “Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè:“Ìwọ yóò mu nínú aago ẹ̀gbọ́n rẹ,aago tí ó tóbi tí ó sì jinnú:yóò mú ìfisẹ̀sín àti ìfiṣe ẹlẹ́yà wá,nítorí tí aago náà gba nǹkan púpọ̀.

33. Ìwọ yóò mu àmupara àti ìbànújẹ́,aago ìparun àti ìsọdahoroaago ẹ̀gbọ́n rẹ Samaríà.

34. Ìwọ yóò mú un, ni àmugbẹ;ìwọ yóò sì fọ sí wẹ́wẹ́ìwọ yóò sì fa ọmú rẹ̀ ya.Èmi ti sọ̀rọ̀ ni Olúwa Olódùmarè wí.

35. “Nítorí náà báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Níwọ̀n bí ìwọ ti gbàgbé mi, tí iwọ sì ti fi mi sí ẹ̀yìn rẹ, ìwọ gbọdọ̀ gba àbájáde ìfẹ́kúfẹ́ àti aṣẹ́wó rẹ.”

36. Olúwa sọ fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, ń jẹ́ ìwọ yóò ṣe ìdájọ́ Óhólà àti Óhólíbà? Nítorí náà dojú kọ wọn nípa ìkórìíra tí wọn ń ṣe,

37. nítorí wọn ti dá ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà ẹ̀jẹ̀ sì wà ní ọwọ́ wọn. Wọn dá ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà pẹ̀lú àwọn orìṣà wọn; kódà wọ́n fi àwọn ọmọ wọn tí wọn bí fúnni ṣe ìrúbọ, gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ fún wọn.

38. Bákan náà ni wọ́n ti ṣe èyí náà sí mi: Ní àkókò kan náà wọn ba ibi mímọ́ mi jẹ́, wọ́n sì lo ọjọ́ ìsinmi mi ní àìmọ́.

39. Ní ọjọ́ náà gan an wọ́n fi àwọn ọmọ wọn rúbọ sí àwọn òrìṣà, wọn wọ ibi mímọ́ mi lọ wọn sì lò ó ní ìlòkúlò. Ìyẹn ní wọn ṣe ní ilé mi.

40. “Wọn tilẹ̀ rán oníṣẹ́ sí àwọn ènìyàn tí wọ́n wá láti ọ̀nà jíjìn, nígbà tí wọ́n dé, ìwọ wẹ ara rẹ fún wọn, ìwọ kún ojú rẹ, ìwọ sì fi ọ̀sọ́ iyebíye sára,

41. Ìwọ jókòó lórí ibùsùn ti o lẹ́wà, pẹ̀lú tábìlì tí a tẹ́ ní iwájú rẹ lórí, èyí tí o gbé tùràrí àti òróró tí ó jẹ́ tèmi kà.

42. “Ariwo ìjọ ènìyàn tí kò bìkítà wà ní àyíká rẹ̀; a mú Sábéánì láti ihà pẹ̀lú àwọn ọkùnrin láti ara àwọn ọ̀pọ̀ èniyàn aláìníláárí, wọ́n sì mú àwọn ẹ̀gbà ọrùn ọwọ́ sí àwọn ọwọ́ obìnrin náà àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀, adé dárádárá sì wà ní orí wọn.

43. Lẹ́yìn náà mo sọ̀rọ̀ nípa èyí tí ó lo ara rẹ̀ ṣá nípa aṣẹ́wó ṣíṣe, ‘Nísìnyí jẹ kí wọn lo o bí aṣẹ́wó, nítorí gbogbo ohun tí ó jẹ́ nìyẹn.’

44. Wọn ba sùn bí ọkùnrin ti bá aṣẹ́wó sùn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe sùn pẹ̀lú obìnrin onífẹ̀kúfẹ̀ẹ́, Óhólà àti Óhólíbà.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 23