Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 22:27-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Àwọn ọmọ aládé àárin rẹ̀ dàbí ikokò ti ń ṣọ̀tẹ̀, láti tàjẹ̀ sílẹ̀, láti pa ọkàn run, láti jèrè àìsòótọ́.

28. Àti àwọn wòlíì rẹ̀ ti ṣẹ̀tàn sí wọn, wọn ń rì iran asán, wọn sì ń fọ àfọ̀sẹ èké sí wọn, wí pé, ‘Báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí’, nígbà tí ó ṣépè Olúwa kò sọ̀rọ̀.

29. Àwọn enìyàn ilẹ̀ náà, tí lo ìwà ìnínilára, wọn sì já olè, wọn sì ni àwọn tálákà àti aláìní lára; nítòótọ́, wọn tí ní àlejò lára láìnídí. Kò sì sí ìdájọ́ òdodó.

30. “Èmi si wá ẹnìkan láàrin wọn, tí ìbá tún odi náà mọ́, tí ìbá dúró ní ibi tí ó ya náà níwájú mi fún ilẹ̀ náà, kí èmi má báà parun: ṣùgbọ́n èmi kò rí ẹnìkan.

31. Nítorí náà ni mo ṣe ma da ìbínú mi sí wọn lórí; máa fí iná ìbínú mi run wọn: mo si ma fi ọ̀nà wọn gbẹ̀san lórí ara wọn, ní Olúwa Ọlọ́run wí.”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 22