Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 15:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ǹjẹ́ a wa lè mú igi lára rẹ̀ ṣe nǹkan ti o wúlò bí? Tàbí kí ènìyàn fi ṣe èèkàn tí yóò fi nǹkan kọ́?

4. Lẹ́yìn èyí, ṣe a jù ú sínú iná gẹ́gẹ́ bí epo ìdáná, gbogbo igun rẹ̀ jóná pẹ̀lú àárin rẹ, ṣé o wà le wúlò fún nǹkan kan mọ́?

5. Tí kò bá wúlò fún nǹkankan nígbà tó wà lódidi, báwo ni yóò ṣe wá wúlò nígbà tíná ti jó o, tó sì dúdú nítorí èéfín?

6. “Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Bí mo ṣe sọ igi àjàrà tó wà láàrin àwọn igi inú igbó yóòkù di igi ìdáná, bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò ṣe ṣe gbogbo ènìyàn tó ń gbé Jérúsálẹ́mù.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 15