Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 13:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé:

2. “Ọmọ ènìyàn sọtẹ́lẹ̀ lòdì sí àwọn wòlíì Ísírẹ́lì tó ń sọtẹ́lẹ̀, kí o sì sọ fún àwọn tí ń sọtẹ́lẹ̀ láti inú èrò ọkàn wọn: ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa!

3. Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Ègbé ni fún àwọn òmùgọ̀ wòlíì tó ń tẹ̀lé ẹ̀mí ara wọn tí wọn kò sì rí nǹkankan!

4. Ísirẹ́lì àwọn wòlíì rẹ dàbí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ nínú pápá.

5. Ẹ kò gòkè láti mọ odi tí ó ya ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì kí wọ́n ba lè dúró gbọin lójú ogun lọ́jọ́ Olúwa.

6. Ìran àti àfọ̀ṣẹ wọn jẹ́ èké. Wọ́n wí pé, “Olúwa wí” nígbà tí Olúwa kò rán wọn, síbẹ̀ wọ́n fẹ́ kí Olúwa mú ọ̀rọ̀ wọn ṣẹ.

7. Ẹ̀yin kò ha ti rí ìran asán, ẹ kò ha ti fọ àfọ̀ṣẹ èké, nígbà tí ẹ sọ pé, “Olúwa wí,” bẹ́ẹ̀ sì ni Èmi kò sọ̀rọ̀?

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 13