Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 1:3-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ àlùfáà Ísíkẹ́lì, ọmọ Búsì wá, létí odò Kébárì ni ilẹ̀ àwọn ará Bábílónì. Níbẹ̀ ni ọwọ́ Olúwa ti wà lára rẹ̀.

4. Mo wò, mo sì rí ìjì tó ń jà bọ̀ láti ìhà àríwá ìkùukùu tó nípọn pẹ̀lú mọ̀nàmọ́ná bù yẹ̀rì pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ rokoṣo tó yí i ká. Àárin iná náà rí bí ìgbà tí irin bá ń bẹ nínú iná,

5. àti láàrin iná náà ni ohun tó dàbí ẹ̀dá alààyè mẹ́rin (4) wà: Ìrísí wọn jẹ́ ti ènìyàn,

6. ṣùgbọ́n ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní ojú mẹ́rin àti ìyẹ́ apá mẹ́rin.

7. Ẹsẹ̀ wọn sì tọ́; àtẹ́lẹsẹ̀ wọn sì rí bí ti ọmọ màlúù, wọ́n sì tàn bí awọ idẹ dídán.

8. Ní abẹ́ ìyẹ́ wọn ní ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọn ní ọwọ́ ènìyàn. Gbogbo àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní ojú àti àwọn ìyẹ́,

9. ìyẹ́ wọn kan ara wọn. Bẹ́ẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn kò padà lọ́nà ibi tí ó ń lọ; ṣùgbọ́n wọ́n ń lọ tààrà ni.

10. Báyìí ni ìrísí ojú àwa ẹ̀dá alààyè yìí: ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ojú ènìyàn, ní apa ọ̀tún wọn, wọ́n ní ojú kìnnìún ní ìhà ọ̀tún, wọ́n ní ojú màlúù ní ìhà òsì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n sì tún ní ojú ẹyẹ idì.

11. Báyìí ni àpèjúwe ojú wọ́n. Ìyẹ́ wọn gbé sókè; ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìyẹ́ méjì, ìyẹ́ ọ̀kan sì kan ti èkejì ni ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́, ìyẹ́ méjì tó sì tún bo ara wọn.

12. Olúkúlùkù wọn ń lọ tààrà. Níbikíbi tí èmi bá ń lọ, ni àwọn náà ń lọ, láì wẹ̀yìn bí wọ́n ti ń lọ.

13. Ìrísí àwọn ẹ̀dá alààyè yìí dàbí ẹyin iná tí ń jó tàbí bí i iná tọ́ọ̀sì. Iná tó ń jó ń lọ sókè lọ sódò láàrin àwọn ẹ̀dá alààyè; iná yìí mọ́lẹ̀ rokoṣo, ó sì ń bù yẹ̀rì yẹ̀rì jáde lára rẹ̀.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 1